Jer 51
51
Ọlọrun Tún Dá Babiloni Lẹ́jọ́ Sí i
1BAYI li Oluwa wi: wò o, emi o rú afẹfẹ iparun soke si Babeli, ati si awọn ti ngbe ãrin awọn ti o dide si mi;
2Emi o si rán awọn alatẹ si Babeli, ti yio fẹ ẹ, nwọn o si sọ ilẹ rẹ̀ di ofo: nitori li ọjọ wahala ni nwọn o wà lọdọ rẹ̀ yikakiri.
3Jẹ ki tafatafa fà ọrun rẹ̀ si ẹniti nfà ọrun, ati si ẹniti o nṣogo ninu ẹ̀wu irin rẹ̀: ẹ má si ṣe dá awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ si, ẹ run gbogbo ogun rẹ̀ patapata.
4Awọn ti a pa yio si ṣubu ni ilẹ awọn ara Kaldea, awọn ti a gun li ọ̀kọ, yio si ṣubu ni ita rẹ̀.
5Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli.
6Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u.
7Babeli jẹ ago wura lọwọ Oluwa, ti o mu gbogbo ilẹ aiye yo bi ọ̀muti: awọn orilẹ-ède ti mu ninu ọti-waini rẹ̀; nitorina ni awọn orilẹ-ède nṣogo.
8Babeli ṣubu, a si fọ ọ lojiji: ẹ hu fun u; ẹ mu ikunra fun irora rẹ̀, bi o jẹ bẹ̃ pe, yio san fun u.
9Awa fẹ wò Babeli sàn, ṣugbọn kò sàn; ẹ kọ̀ ọ silẹ, ki ẹ si jẹ ki a lọ, olukuluku si ilẹ rẹ̀: nitori ẹbi rẹ̀ de ọrun, a si gbe e soke de awọsanma.
10Oluwa mu ododo wa jade; ẹ wá, ẹ jẹ ki a si kede iṣẹ Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni.
11Pọ́n ọfa mu: mu asà li ọwọ: Oluwa ti ru ẹmi awọn ọba Media soke: nitori ipinnu rẹ̀ si Babeli ni lati pa a run, nitoripe igbẹsan Oluwa ni, igbẹsan fun tempili rẹ̀.
12Gbé asia soke lori odi Babeli, mu awọn iṣọ lagbara, mu awọn oluṣọ duro, ẹ yàn ẹ̀bu: nitori Oluwa gbero, o si ṣe eyi ti o wi si awọn olugbe Babeli.
13Iwọ ẹniti ngbe ẹba omi pupọ, ti o pọ ni iṣura, opin rẹ de, iwọn ikogun-ole rẹ kún.
14Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ bura pe, ni kikún emi o fi enia kún ọ gẹgẹ bi ẹlẹnga; nwọn o si pa ariwo ogun lori rẹ.
Orin Ìyìn sí Ọlọrun
15On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti ṣe ipinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si tẹ́ awọn ọrun nipa oye rẹ̀.
16Nigbati o ba san ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ li oju ọrun; o si mu kũku goke lati opin aiye wá, o dá manamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.
17Aṣiwere ni gbogbo enia, nitori oye kò si; oju tì gbogbo alagbẹdẹ nitori ere, nitori ere didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu wọn.
18Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: ni ìgba ibẹ̀wo wọn, nwọn o ṣegbe.
19Ipin Jakobu kò dabi wọn: nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo: Israeli si ni ẹ̀ya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
Òòlù OLUWA
20Iwọ ni òlù mi, ohun elo-ogun: emi o fi ọ fọ awọn orilẹ-ède tũtu, emi o si fi ọ pa awọn ijọba run;
21Emi o si fi ọ fọ ẹṣin ati ẹlẹṣin tũtu; emi o si fi ọ fọ kẹ̀kẹ ati ẹniti o gùn u tũtu;
22Emi o si fi ọ fọ ọkunrin ati obinrin tũtu; emi o si fi ọ fọ arugbo ati ọmọde tũtu; emi o si fi ọ fọ ọdọmọkunrin ati wundia tũtu;
23Emi o si fi ọ fọ oluṣọ-agutan ati agbo-ẹran rẹ̀ tũtu, emi o si fi ọ fọ àgbẹ ati àjaga-malu rẹ̀ tũtu; emi o si fi ọ fọ awọn balẹ ati awọn ijoye tũtu.
Ìjìyà Babiloni
24Ṣugbọn emi o si san fun Babeli ati fun gbogbo awọn olugbe Kaldea gbogbo ibi wọn, ti nwọn ti ṣe ni Sioni li oju nyin, li Oluwa wi.
25Wo o, emi dojukọ ọ, iwọ oke ipanirun! li Oluwa wi, ti o pa gbogbo ilẹ aiye run; emi o si nà ọwọ mi sori rẹ, emi o si yi ọ lulẹ lati ori apata wá, emi o si ṣe ọ ni oke jijona.
26Ki nwọn ki o má le mu okuta igun ile, tabi okuta ipilẹ ninu rẹ, ṣugbọn iwọ o di ahoro lailai, li Oluwa wi.
27Ẹ gbe asia soke ni ilẹ na, fọn ipè lãrin awọn orilẹ-ède, sọ awọn orilẹ-ède di mimọ́ sori rẹ̀, pè awọn ijọba Ararati, Minni, ati Aṣkinasi sori rẹ̀, yàn balogun sori rẹ̀, mu awọn ẹṣin wá gẹgẹ bi ẹlẹnga ẹlẹgun.
28Sọ awọn orilẹ-ède pẹlu awọn ọba Media di mimọ́ sori rẹ̀, awọn balẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.
29Ilẹ yio si mì, yio si kerora: nitori gbogbo èro Oluwa ni a o mú ṣẹ si Babeli, lati sọ ilẹ Babeli di ahoro laini olugbe.
30Awọn akọni Babeli ti dẹkun jijà, nwọn ti joko ninu ile-odi wọn; agbara wọn ti tán; nwọn di obinrin, nwọn tinabọ ibugbe rẹ̀; a ṣẹ́ ikere rẹ̀.
31Ẹnikan ti nsare yio sare lọ lati pade ẹnikeji ti nsare, ati onṣẹ kan lati pade onṣẹ miran, lati jiṣẹ fun ọba Babeli pe: a kó ilu rẹ̀ ni iha gbogbo.
32Ati pe, a gbà awọn asọda wọnni, nwọn si ti fi ifefe joná, ẹ̀ru si ba awọn ọkunrin ogun.
33Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Ọmọbinrin Babeli dabi ilẹ ipaka, li akoko ti a o pa ọka lori rẹ̀: sibẹ ni igba diẹ si i, akoko ikore rẹ̀ mbọ fun u.
34Nebukadnessari, ọba Babeli, ti jẹ mi run, o ti tẹ̀ mi mọlẹ, o ti ṣe mi ni ohun-elo ofo, o ti gbe mi mì gẹgẹ bi ọ̀wawa, o ti fi ohun didara mi kún ikun rẹ̀, o ti le mi jade.
35Ki ìwa-ika ti a hù si mi ati ẹran-ara mi ki o wá sori Babeli, bẹ̃ni iwọ olugbe Sioni yio wi; ati ẹ̀jẹ mi lori awọn olugbe, ara Kaldea, bẹ̃ni iwọ, Jerusalemu, yio wi.
OLUWA Yóo Ran Israẹli lọ́wọ́
36Nitorina bayi ni Oluwa wi; Wò o, emi o gba ijà rẹ jà, emi o si gba ẹsan rẹ, emi o si gbẹ okun rẹ̀, emi o si mu gbogbo orisun rẹ̀ gbẹ.
37Babeli yio si di òkiti àlapa, ibugbe ọ̀wawa, iyanu, ẹsin, laini olugbe.
38Nwọn o jumọ bú bi kiniun: nwọn o si ke bi ọmọ kiniun.
39Ninu oru wọn li emi o ṣe ase ohun mimu fun wọn, emi o si mu wọn yo bi ọ̀muti, ki nwọn ki o le ma yọ̀, ki nwọn ki o si sun orun lailai, ki nwọn ki o má si jí mọ́, li Oluwa wi.
40Emi o si mu wọn wá bi ọdọ-agutan si ibi pipa, bi àgbo pẹlu obukọ.
Ìpín Babiloni
41Bawo li a kó Ṣeṣaki! bawo li ọwọ wọn ṣe tẹ iyìn gbogbo ilẹ aiye! bawo ni Babeli ṣe di iyanu lãrin awọn orilẹ-ède!
42Okun wá sori Babeli: a si fi ọ̀pọlọpọ riru omi rẹ̀ bò o mọlẹ.
43Ilu rẹ̀ ni ahoro, ilẹ gbigbe, ati aginju: ilẹ ninu eyiti ẹnikẹni kò gbe, bẹ̃ni ọmọ enia kò kọja nibẹ.
44Nitori emi o jẹ Beli niya ni Babeli, emi o si mu eyiti o ti gbemì jade li ẹnu rẹ̀: awọn orilẹ-ède kì yio jumọ ṣàn lọ pọ si ọdọ rẹ̀ mọ: lõtọ odi Babeli yio wó.
45Enia mi, ẹ jade ni ãrin rẹ̀, ki olukuluku nyin si gba ẹmi rẹ̀ là kuro ninu ibinu gbigbona Oluwa!
46Ati ki ọkàn nyin má ba rẹ̀wẹsi, ati ki ẹ má ba bẹ̀ru, nitori iró ti a o gbọ́ ni ilẹ na; nitori iró na yio de li ọdun na, ati lẹhin na iró yio de li ọdun keji, ati ìwa-ika ni ilẹ na, alakoso yio dide si alakoso.
47Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, ti emi o bẹ awọn ere fifin Babeli wò: oju yio si tì gbogbo ilẹ rẹ̀, gbogbo awọn olupa rẹ̀ yio si ṣubu li ãrin rẹ̀.
48Ọrun ati aiye, ati gbogbo ohun ti o wà ninu wọn, yio si kọrin lori Babeli: nitori awọn afiniṣeijẹ yio wá sori rẹ̀ lati ariwa, li Oluwa wi.
49Gẹgẹ bi Babeli ti mu ki awọn olupa Israeli ṣubu, bẹ̃ gẹgẹ li awọn olupa gbogbo ilẹ aiye yio ṣubu.
Ọlọrun Ranṣẹ sí Israẹli ní Babiloni
50Ẹnyin ti o ti bọ lọwọ idà, ẹ lọ, ẹ má duro: ẹ ranti Oluwa li okere, ẹ si jẹ ki Jerusalemu wá si ọkàn nyin.
51Oju tì wa, nitoripe awa ti gbọ́ ẹ̀gan: itiju ti bò loju, nitori awọn alejo wá sori ohun mimọ́ ile Oluwa.
52Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o ṣe ibẹwo lori awọn ere fifin rẹ̀: ati awọn ti o gbọgbẹ yio si mã gbin ja gbogbo ilẹ rẹ̀.
53Bi Babeli tilẹ goke lọ si ọrun, bi o si ṣe olodi li oke agbara rẹ̀, sibẹ awọn afiniṣeijẹ yio ti ọdọ mi tọ̀ ọ wá, li Oluwa wi.
Ìparun Túbọ̀ Dé Bá Babiloni
54Iró igbe lati Babeli! ati iparun nla lati ilẹ awọn ara Kaldea!
55Nitoripe Oluwa ti ṣe Babeli ni ijẹ, o si ti pa ohùn nla run kuro ninu rẹ̀; riru wọn si nho bi omi pupọ, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.
56Nitoripe afiniṣeijẹ de sori rẹ̀, ani sori Babeli; a mu awọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nitori Ọlọrun ẹsan ni Oluwa, yio san a nitõtọ.
57Emi o si mu ki awọn ijoye rẹ̀ yo bi ọ̀muti, ati awọn ọlọgbọn rẹ̀, awọn bàlẹ rẹ̀, ati awọn alakoso rẹ̀, ati awọn akọni rẹ̀, nwọn o si sun orun lailai, nwọn kì o si ji mọ́, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun.
58Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: odi Babeli gbigboro li a o wó lulẹ patapata, ẹnu-bode giga rẹ̀ li a o si fi iná sun: tobẹ̃ ti awọn enia ti ṣiṣẹ lasan, ati awọn orilẹ-ède ti ṣiṣẹ fun iná, ti ãrẹ si mu wọn.
Jeremiah Ranṣẹ sí Babiloni
59Ọ̀rọ ti Jeremiah woli paṣẹ fun Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maaseiah, nigbati o nlọ niti Sedekiah, ọba Judah, si Babeli li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. Seraiah yi si ni ijoye ibudo.
60Jeremiah si kọ gbogbo ọ̀rọ-ibi ti yio wá sori Babeli sinu iwe kan, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti a kọ si Babeli.
61Jeremiah si sọ fun Seraiah pe, nigbati iwọ ba de Babeli, ki iwọ ki o si wò, ki iwọ ki o si ka gbogbo ọ̀rọ wọnyi.
62Ki iwọ ki o si wipe, Oluwa, iwọ ti sọ̀rọ si ibi yi, lati ke e kuro, ki ẹnikẹni má ṣe gbe inu rẹ̀, ati enia ati ẹran, nitori pe yio di ahoro lailai.
63Yio si ṣe nigbati iwọ ba pari kikà iwe yi tan, ki iwọ ki o di okuta mọ ọ, ki o si sọ ọ si ãrin odò Ferate:
64Ki iwọ si wipe, Bayi ni Babeli yio rì, kì o si tun dide kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori rẹ̀: ãrẹ̀ yio si mu wọn. Titi de ihin li ọ̀rọ Jeremiah.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 51: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.