Jer 47
47
Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia
1Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah woli wá, si awọn ara Filistia, ki Farao ki o to kọlu Gasa.
2Bayi li Oluwa wi; Wò o, omi dide lati ariwa, yio si jẹ kikun omi akunya, yio si ya bo ilẹ na, ati gbogbo ẹkún inu rẹ̀; ilu na, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀: nigbana ni awọn enia yio kigbe, gbogbo awọn olugbe ilẹ na yio si hu.
3Nipa ariwo titẹlẹ patakò ẹsẹ alagbara ẹṣin rẹ̀, nipa iró nla kẹ̀kẹ rẹ̀, ati nipa ariwo nla ayika kẹ̀kẹ rẹ̀; awọn baba kì yio bojuwo ẹhin wò awọn ọmọ wọn nitori ọwọ́ rirọ;
4Nitori ọjọ na ti mbọ lati pa gbogbo awọn ara Filistia run, ati lati ke gbogbo oluranlọwọ ti o kù kuro lọdọ Tire ati Sidoni: nitori Oluwa yio ṣe ikogun awọn ara Filistia, ani iyokù erekuṣu Kaftori.
5Ipári de si Gasa, Aṣkeloni ti dahoro, pẹlu iyokù afonifoji wọn: iwọ o ti ṣa ara rẹ lọgbẹ pẹ to?
6Ye! iwọ idà Oluwa, yio ti pẹ to ki iwọ ki o to gbe jẹ? tẹ ara rẹ bọ inu akọ rẹ, simi! ki o si dakẹ!
7Ṣugbọn bawo li o ti ṣe le gbe jẹ, nigbati Oluwa ti paṣẹ fun u si Aṣkeloni, ati si ebute okun, nibẹ li o ti ran a lọ!
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 47: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.