Jer 4
4
Ìpè sí Ìrònúpìwàdà
1Israeli bi iwọ o ba yipada, li Oluwa wi, yipada sọdọ mi; ati bi iwọ o ba mu irira rẹ kuro niwaju mi, iwọ kì o si rìn kiri:
2Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.
3Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ọkunrin Juda, ati Jerusalemu pe, tú ilẹ titun fun ara nyin, ki ẹ má si gbìn lãrin ẹ̀gun.
4Ẹ kọ ara nyin ni ilà fun Oluwa, ki ẹ si mu awọ ikọla ọkàn nyin kuro, ẹnyin enia Juda ati olugbe Jerusalemu, ki ikannu mi ki o má ba jade bi iná, ki o si jo tobẹ̃ ti kò si ẹniti o le pa a, nitori buburu iṣe nyin.
A fi Ogun Halẹ̀ mọ́ Juda
5Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì.
6Ẹ gbé ọpagun soke siha Sioni; ẹ kuro, ẹ má duro: nitori emi o mu buburu lati ariwa wá pẹlu ibajẹ nlanla.
7Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe.
8Nitori eyi, di amure aṣọ ọ̀fọ, pohùnrere ki o si sọkun: nitori ibinu gbigbona Oluwa kò lọ kuro lọdọ wa.
9Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ọkàn ọba yio nù, ati ọkàn awọn ijoye: awọn alufa yio si dãmu, hà yio si ṣe awọn woli.
10Nigbana ni mo wipe, Ye! Oluwa Ọlọrun! nitõtọ iwọ ti tan awọn enia yi ati Jerusalemu jẹ gidigidi, wipe, Ẹnyin o ni alafia; nigbati idà wọ inu ọkàn lọ.
11Nigbana ni a o wi fun awọn enia yi ati fun Jerusalemu pe, Ẹfũfu gbigbona lati ibi giga ni iju niha ọmọbinrin enia mi, kì iṣe lati fẹ, tabi lati fẹnù.
12Ẹfũfu ti o lagbara jù wọnyi lọ yio fẹ fun mi: nisisiyi emi pẹlu yio sọ̀rọ idajọ si wọn.
Àwọn Ọ̀tá yí Juda Ká
13Sa wò o, on o dide bi awọsanma, kẹ̀kẹ rẹ̀ yio dabi ìji: ẹṣin rẹ̀ yara jù idì lọ. Egbe ni fun wa! nitori awa di ijẹ.
14Jerusalemu! wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ là. Yio ti pẹ to ti iro asan yio wọ̀ si inu rẹ.
15Nitori ohùn kan kede lati Dani wá, o si pokiki ipọnju lati oke Efraimu.
16Ẹ wi fun awọn orilẹ-ède; sa wò o, kede si Jerusalemu, pe, awọn ọluṣọ-ogun ti ilẹ jijin wá, nwọn si sọ ohùn wọn jade si ilu Juda.
17Bi awọn ti nṣọ oko, bẹ̃ni nwọn wà yi i kakiri: nitori o ti ṣọtẹ̀ si mi, li Oluwa wi.
18Ìwa rẹ ati iṣe rẹ li o ti mu gbogbo ohun wọnyi bá ọ; eyi ni buburu rẹ, nitoriti o korò, nitoriti o de ọkàn rẹ.
Ìbànújẹ́ Jeremiah nítorí Àwọn Eniyan Rẹ̀
19Inu mi, inu mi! ẹ̀dun dùn mi jalẹ de ọkàn mi; ọkàn mi npariwo ninu mi; emi kò le dakẹ, Nitoriti iwọ, ọkàn mi, ngbọ́ iro fère, ati idagiri ogun.
20Iparun lori iparun ni a nke; nitori gbogbo ilẹ li o ti parun, lojiji ni agọ mi di ijẹ, pẹlu aṣọ ikele mi ni iṣẹju kan.
21Yio ti pẹ to ti emi o ri ọpagun, ti emi o si gbọ́ iro fère?
22Nitori òpe li enia mi, nwọn kò mọ̀ mi; alaimoye ọmọ ni nwọn iṣe, nwọn kò si ni ìmọ: nwọn ni ọgbọ́n lati ṣe ibi, ṣugbọn oye ati ṣe rere ni nwọn kò ni.
Ìran tí Jeremiah Rí nípa Ìparun Tí Ń Bọ̀
23Mo bojuwo aiye, sa wò o, o wà ni jũju, o si ṣofo; ati ọrun, imọlẹ kò si lara rẹ̀.
24Mo bojuwo gbogbo oke nla, sa wò o, o warìri ati gbogbo oke kekere mì jẹjẹ.
25Mo bojuwo, sa wò o, kò si enia kan, pẹlupẹlu gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun sa lọ.
26Mo bojuwo, sa wò o, Karmeli di aginju, ati gbogbo ilu rẹ̀ li o wó lulẹ, niwaju Oluwa ati niwaju ibinu rẹ̀ gbigbona.
27Nitori bayi li Oluwa wi pe: Gbogbo ilẹ ni yio di ahoro; ṣugbọn emi kì yio ṣe ipari tan.
28Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀.
29Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn.
30Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ.
31Nitori mo ti gbọ́ ohùn kan bi ti obinrin ti nrọbi, irora bi obinrin ti nbi akọbi ọmọ rẹ̀, ohùn ọmọbinrin Sioni ti npohùnrere ẹkun ara rẹ̀, ti o nnà ọwọ rẹ̀ wipe: Egbé ni fun mi nisisiyi nitori ãrẹ mu mi li ọkàn, nitori awọn apania.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 4: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.