Jer 35

35
Jeremiah ati Àwọn Ọmọ Rekabu
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe:
2Lọ si ile awọn ọmọ Rekabu, ki o si ba wọn sọ̀rọ, ki o si mu wọn wá si ile Oluwa, si ọkan ninu iyara wọnni, ki o si fun wọn li ọti-waini mu.
3Nigbana ni mo mu Jaasaniah, ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ile awọn ọmọ Rekabu;
4Mo si mu wọn wá si ile Oluwa, sinu iyara awọn ọmọ Hanani, ọmọ Igdaliah, enia Ọlọrun, ti o wà lẹba iyara awọn ijoye, ti o wà li oke iyara Maaseiah, ọmọ Ṣallumu, olutọju ẹnu-ọ̀na,
5Mo si gbe ìkoko ti o kún fun ọti-waini pẹlu ago, ka iwaju awọn ọmọ ile Rekabu, mo si wi fun wọn pe: Ẹ mu ọti-waini.
6Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio mu ọti-waini, nitori Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa, paṣẹ fun wa pe: Ẹnyin kò gbọdọ mu ọti-waini, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin lailai.
7Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ kọ́ ile, tabi ki ẹ fun irugbin, tabi ki ẹ gbin ọgba-àjara, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ni; ṣugbọn ni gbogbo ọjọ nyin li ẹnyin o ma gbe inu agọ; ki ẹnyin ki o le wà li ọjọ pupọ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nṣe atipo.
8Bayi li awa gbà ohùn Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa gbọ́ ninu gbogbo eyiti o palaṣẹ fun wa, ki a má mu ọti-waini ni gbogbo ọjọ wa, awa, awọn aya wa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa;
9Ati ki a má kọ ile lati gbe; bẹ̃ni awa kò ni ọgba-ajara, tabi oko, tabi ohùn ọgbin.
10Ṣugbọn awa ngbe inu agọ, a si gbọran, a si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jonadabu, baba wa, palaṣẹ fun wa.
11O si ṣe, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli, goke wá si ilẹ na, ni awa wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si Jerusalemu, nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Kaldea, ati nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Siria: bẹ̃ni awa ngbe Jerusalemu.
12Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá wipe:
13Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Lọ, ki o si sọ fun awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu pe, Ẹnyin kì yio ha gbà ẹkọ lati feti si ọ̀rọ mi? li Oluwa wi.
14Ọ̀rọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, ti o pa laṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o má mu ọti-waini, ni a mu ṣẹ; nwọn kò si mu ọti-waini titi di oni yi. Nitoriti nwọn gbọ́ ofin baba wọn, emi si ti nsọ̀rọ fun nyin, emi dide ni kutukutu, emi nsọ: ṣugbọn ẹnyin kò fetisi ti emi.
15Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.
16Lõtọ awọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, pa ofin baba wọn mọ, ti o pa laṣẹ fun wọn; ṣugbọn awọn enia yi kò gbọ́ ti emi:
17Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o mu wá sori Juda, ati sori gbogbo olugbe Jerusalemu, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn; nitori ti emi ti ba wọn sọ̀rọ, nwọn kò si gbọ́; mo si ti pè wọn, nwọn kò si dahùn.
18Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin:
19Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Jonadabu, ọmọ Rekabu kì yio fẹ ọkunrin kan kù lati duro niwaju mi lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 35: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa