Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun. Kì iṣe bi majẹmu na ti emi ba baba wọn dá li ọjọ na ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti nwọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ alakoso wọn sibẹ, li Oluwa wi; Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi. Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi kì o si ranti ẹ̀ṣẹ wọn mọ.
Kà Jer 31
Feti si Jer 31
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jer 31:31-34
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò