Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o tun mu igbekun agọ Jakobu pada bọ̀; emi o si ṣãnu fun ibugbe rẹ̀; a o si kọ́ ilu na sori okiti rẹ̀, a o si ma gbe ãfin gẹgẹ bi ilana rẹ̀. Ati lati inu wọn ni ọpẹ́ ati ohùn awọn ti nyọ̀ yio ti jade: emi o si mu wọn bi si i, nwọn kì o si jẹ diẹ; emi o ṣe wọn li ogo pẹlu, nwọn kì o si kere. Awọn ọmọ wọn pẹlu yio ri bi ti iṣaju, ijọ wọn li a o fi idi rẹ̀ mulẹ niwaju mi, emi o si jẹ gbogbo awọn ti o ni wọn lara niya. Ọlọla rẹ̀ yio si jẹ lati inu ara wọn wá, alakoso rẹ̀ lati ãrin rẹ̀; emi o si mu u sunmọ tosi, on o si sunmọ ọdọ mi: nitori tani ẹniti o mura ọkàn rẹ̀ lati sunmọ ọdọ mi? li Oluwa wi. Ẹnyin o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin. Wò o, afẹfẹ iji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori oluṣe-buburu. Ibinu kikan Oluwa kì o pada, titi on o fi ṣe e, ati titi on o fi mu èro ọkàn rẹ̀ ṣẹ: li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.
Kà Jer 30
Feti si Jer 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jer 30:18-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò