Jer 30
30
Ìlérí OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe.
2Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, pe, Iwọ kọ gbogbo ọ̀rọ ti mo ti ba ọ sọ sinu iwe kan.
3Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu igbekun awọn enia mi, Israeli ati Juda, pada, li Oluwa wi: emi o si mu ki nwọn pada bọ̀ si ilẹ ti emi fi fun awọn baba wọn, nwọn o si ni i.
4Wọnyi si li ọ̀rọ ti Oluwa sọ niti Israeli ati niti Juda.
5Nitori bayi li Oluwa wi; Awa ti gbọ́ ohùn ìwa-riri, ẹ̀ru, kì si iṣe ti alafia.
6Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkunrin a mã rọbi ọmọ: Ẽṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkunrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn, bi obinrin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro?
7Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹ̃ ti kò si ọkan bi iru rẹ̀: o jẹ àkoko wahala fun Jakobu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ̀.
8Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi o si ṣẹ àjaga kuro li ọrùn rẹ, emi o si ja ìde rẹ, awọn alejo kì yio si mu ọ sìn wọn mọ:
9Ṣugbọn nwọn o ma sin Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn, ẹniti emi o gbe kalẹ fun wọn.
10Njẹ nisisiyi, má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi; ki o má si fòya, iwọ Israeli: nitorina sa wò o, emi o gbà ọ lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati igbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì yio si dẹruba a.
11Nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ: bi emi tilẹ ṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi kì yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn, emi kì o jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.
12Nitori bayi li Oluwa wi, Ifarapa rẹ jẹ aiwotan, ọgbẹ rẹ si jẹ aijina.
13Kò si ẹniti o gba ọ̀ran rẹ rò, lati dì i, ọja imularada kò si.
14Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,
15Ẽṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikãnu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ; ẹ̀ṣẹ rẹ si pọ̀ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ.
16Nitorina gbogbo awọn ti o jẹ ọ, li a o jẹ; ati gbogbo awọn ọta rẹ, olukuluku wọn, ni yio lọ si igbekun: ati awọn ti o kó ọ yio di kikó, ati gbogbo awọn ti o fi ọ ṣe ijẹ li emi o fi fun ijẹ.
17Nitori emi o fi ọja imularada lè ọ, emi o si wò ọgbẹ rẹ san, li Oluwa wi; nitori nwọn pè ọ li ẹniti a le jade; Sioni, ti ẹnikan kò ṣafẹri rẹ̀!
18Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o tun mu igbekun agọ Jakobu pada bọ̀; emi o si ṣãnu fun ibugbe rẹ̀; a o si kọ́ ilu na sori okiti rẹ̀, a o si ma gbe ãfin gẹgẹ bi ilana rẹ̀.
19Ati lati inu wọn ni ọpẹ́ ati ohùn awọn ti nyọ̀ yio ti jade: emi o si mu wọn bi si i, nwọn kì o si jẹ diẹ; emi o ṣe wọn li ogo pẹlu, nwọn kì o si kere.
20Awọn ọmọ wọn pẹlu yio ri bi ti iṣaju, ijọ wọn li a o fi idi rẹ̀ mulẹ niwaju mi, emi o si jẹ gbogbo awọn ti o ni wọn lara niya.
21Ọlọla rẹ̀ yio si jẹ lati inu ara wọn wá, alakoso rẹ̀ lati ãrin rẹ̀; emi o si mu u sunmọ tosi, on o si sunmọ ọdọ mi: nitori tani ẹniti o mura ọkàn rẹ̀ lati sunmọ ọdọ mi? li Oluwa wi.
22Ẹnyin o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin.
23Wò o, afẹfẹ iji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori oluṣe-buburu.
24Ibinu kikan Oluwa kì o pada, titi on o fi ṣe e, ati titi on o fi mu èro ọkàn rẹ̀ ṣẹ: li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 30: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.