Jer 3

3
Israẹli Alaiṣododo
1SA wò o, bi a wipe ọkunrin kan kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti aya na si kuro lọdọ rẹ̀, ti o si di aya ẹlomiran, ọkunrin na le tun tọ̀ ọ wá? ilẹ na kì yio di ibajẹ gidigidi? ṣugbọn iwọ ti ba ayanfẹ pupọ ṣe panṣaga, iwọ o tun tọ̀ mi wá! li Oluwa wi.
2Gbe oju rẹ soke si ibi giga wọnnì, ki o si wò, nibo ni a kò ti bà ọ jẹ? Iwọ joko de wọn li oju ọ̀na, bi ara Arabia kan ni iju, iwọ si ti fi agbere ati ìwa buburu rẹ bà ilẹ na jẹ.
3Nitorina emi fa ọ̀wara òjo sẹhin, kò si òjo arọkuro, sibẹ iwọ ni iwaju agbere, iwọ kọ̀ lati tiju.
4Lõtọ lati isisiyi, iwọ kì yio ha pè mi pe, Baba mi! iwọ li ayanfẹ ìgba-ewe mi?
5On o ha pa ibinu rẹ̀ mọ lailai? yio pa a mọ de opin? sa wò o, bayi ni iwọ ti wi, ṣugbọn iwọ ṣe ohun buburu li aidẹkun.
Israẹli ati Juda Gbọdọ̀ Ronu piwa da
6Oluwa si wi fun mi ni igba Josiah ọba, pe, Iwọ ri ohun ti Israeli apẹhinda ti ṣe? o ti gun ori oke giga gbogbo, ati labẹ gbogbo igi tutu, nibẹ li o ti ṣe panṣaga.
7Emi si wipe, lẹhin ti o ti ṣe gbogbo ohun wọnyi tan, yio yipada si mi, ṣugbọn kò yipada, Juda alarekereke arabinrin rẹ̀ si ri i.
8Emi si wò pe, nitori gbogbo wọnyi ti Israeli apẹhinda ti ṣe agbere, ti mo kọ̀ ọ silẹ ti emi si fun u ni iwe-ikọsilẹ, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò bẹ̀ru, o si nṣe agbere lọ pẹlu.
9O si ṣe nitori okìki àgbere rẹ̀ li o fi bà ilẹ jẹ, ti o si ṣe àgbere tọ̀ okuta ati igi lọ.
10Lẹhin gbogbo wọnyi, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò yipada si mi tọkàntọkàn ṣugbọn li agabagebe; li Oluwa wi.
11Oluwa si wi fun mi pe, Israeli apẹhinda, ti dá ara rẹ̀ li are ju Juda alarekereke lọ.
12Lọ ki o si kede ọ̀rọ wọnyi ni iha ariwa, ki o si wipe, Yipada iwọ Israeli, apẹhinda, li Oluwa wi, emi kì yio jẹ ki oju mi ki o korò si ọ; nitori emi ni ãnu, li Oluwa wi, emi kì o si pa ibinu mi mọ titi lai.
13Sa jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ pe, iwọ ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe, o si tú ọ̀na rẹ ka fun awọn alejo labẹ igi tutu gbogbo, ṣugbọn ẹnyin kò gba ohùn mi gbọ́, li Oluwa wi.
14Pada, ẹnyin apẹhinda ọmọ, li Oluwa wi, nitori emi gbe nyin ni iyawo; emi o si mu nyin, ọkan ninu ilu kan, ati meji ninu idile kan; emi o si mu nyin wá si Sioni.
15Emi o si fun nyin li oluṣọ-agutan gẹgẹ bi ti inu mi, ti yio fi ìmọ ati oye bọ́ nyin.
16Yio si ṣe nigbati ẹnyin ba pọ̀ si i, ti ẹ si dàgba ni ilẹ na, li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi; nwọn kì yio si tun le wipe, Apoti-ẹri majẹmu Oluwa; bẹ̃ni kì yio wọ inu wọn, nwọn kì yio si ranti rẹ̀, nwọn kì yio tọ̀ ọ wá pẹlu, bẹ̃ni a kì yio si tun ṣe e mọ.
17Nigbana ni nwọn o pè Jerusalemu ni itẹ Oluwa; gbogbo orilẹ-ède yio kọja tọ̀ ọ wá si orukọ Oluwa, si Jerusalemu, bẹ̃ni nwọn kì yio rìn mọ nipa agidi ọkàn buburu wọn,
18Li ọjọ wọnnì, ile Juda yio rin pẹlu ile Israeli, nwọn o jumọ wá lati ilẹ ariwa, si ilẹ ti emi ti fi fun awọn baba nyin li ogún.
Ìbọ̀rìṣà Àwọn Eniyan Ọlọrun
19Emi si wipe, Bawo li emi o ṣe gbe ọ kalẹ pẹlu awọn ọmọ, ati lati fun ọ ni ilẹ ayanfẹ, ogún daradara, ani ogún awọn orilẹ-ède? Emi si wipe, Iwọ o pè mi ni, Baba mi! iwọ kì o si pada kuro lọdọ mi.
20Nitõtọ gẹgẹ bi aya ti ifi arekereke lọ kuro lọdọ ọkọ rẹ̀, bẹ̃ni ẹnyin ti hùwa arekereke si mi, iwọ ile Israeli: li Oluwa wi.
21A gbọ́ ohùn kan lori ibi giga, ẹkun, ani ẹ̀bẹ awọn ọmọ Israeli pe: nwọn ti bà ọ̀na wọn jẹ, nwọn si ti gbagbe Oluwa, Ọlọrun wọn.
22Yipada, ẹnyin ọmọ apẹhinda, emi o si wò ipẹhinda nyin sàn; Sa wò o, awa tọ̀ ọ wá, nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun wa!
23Lotitọ asan ni eyi ti o ti oke wá, ani ọ̀pọlọpọ oke giga, lõtọ ninu Oluwa Ọlọrun wa ni igbala Israeli wà.
24Ṣugbọn ohun itiju oriṣa ti jẹ ère iṣẹ awọn baba wa lati igba ewe wa wá, ọwọ́-ẹran wọn ati agbo-ẹran wọn, pẹlu ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.
25Awa dubulẹ ninu itiju wa, rudurudu wa bò wa mọlẹ, nitoriti awa ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun wa, awa pẹlu awọn baba wa, lati igba ewe wa wá, titi di oni yi, awa kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀