Jer 29:4-14

Jer 29:4-14 YBCV

Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi fun gbogbo awọn ti a kó ni igbekun lọ, ti emi mu ki a kó lọ lati Jerusalemu si Babeli; Ẹ kọ́ ile ki ẹ si ma gbe inu wọn; ẹ gbìn ọgba, ki ẹ si mã jẹ eso wọn; Ẹ fẹ́ aya, ki ẹ si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ si fẹ́ aya fun awọn ọmọ nyin, ẹ si fi awọn ọmọbinrin nyin fun ọkọ, ki nwọn ki o le mã bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ le mã pọ si i nibẹ, ki ẹ má si dínkù. Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki awọn woli nyin ti o wà lãrin nyin ati awọn alafọṣẹ nyin tàn nyin jẹ, ki ẹ má si feti si alá nyin ti ẹnyin lá. Nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi: emi kò rán wọn, li Oluwa wi. Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi. Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti. Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin. Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi. Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.