Jer 27
27
A Pe Jeremiah Lẹ́jọ́
1LI atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọ̀dọ Oluwa wipe,
2Bayi li Oluwa wi fun mi; Ṣe ijara ati àjaga-ọrùn fun ara rẹ, ki o si fi wọ ọrùn rẹ.
3Ki o rán wọn lọ si ọdọ ọba Edomu, ati si ọba Moabu, ati si ọba awọn ọmọ Ammoni, ati si ọba Tire, ati si ọba Sidoni, lọwọ awọn ikọ̀ ti o wá si Jerusalemu sọdọ Sedekiah, ọba Juda.
4Ki o si paṣẹ fun wọn lati wi fun awọn oluwa wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Bayi li ẹnyin o wi fun awọn oluwa nyin pe;
5Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi.
6Njẹ nisisiyi, emi fi gbogbo ilẹ yi le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi: ati ẹranko igbẹ ni mo fi fun u pẹlu lati sin i.
7Ati orilẹ-ède gbogbo ni yio sin on, ati ọmọ rẹ̀ ati ọmọ-ọmọ rẹ̀, titi di ìgba ti akoko ilẹ tirẹ̀ yio de; lara rẹ̀ ni orilẹ-ède pupọ ati awọn ọba nla yio jẹ.
8Yio si ṣe, orilẹ-ède ati ijọba ti kì yio sin Nebukadnessari ọba Babeli, ti kì yio fi ọrùn wọn si abẹ àjaga ọba Babeli, orilẹ-ède na li emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, jẹ niya, li Oluwa wi, titi emi o fi run wọn nipa ọwọ rẹ̀.
9Nitorina ẹ máṣe fi eti si awọn woli nyin, tabi si awọn alafọṣẹ nyin, tabi si awọn alála, tabi si awọn oṣo nyin, tabi awọn ajẹ nyin ti nsọ fun nyin pe, Ẹnyin kì o sin ọba Babeli:
10Nitori nwọn sọ-asọtẹlẹ eke fun nyin, lati mu nyin jina réré kuro ni ilẹ nyin, ki emi ki o lè lé nyin jade, ti ẹnyin o si ṣegbe.
11Ṣugbọn orilẹ-ède na ti o mu ọrùn rẹ̀ wá si abẹ àjaga ọba Babeli, ti o si sìn i, on li emi o jẹ ki o joko ni ilẹ wọn, li Oluwa wi, yio si ro o, yio si gbe ibẹ.
12Emi si wi fun Sedekiah, ọba Juda, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi, pe, Ẹ mu ọrùn nyin si abẹ àjaga ọba Babeli, ki ẹ sin i, pẹlu awọn enia rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin o yè.
13Ẽṣe ti ẹnyin o kú, iwọ, ati enia rẹ, nipa idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, bi Oluwa ti sọ si orilẹ-ède ti kì yio sin ọba Babeli.
14Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
15Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin.
16Pẹlupẹlu emi sọ fun awọn alufa ati fun gbogbo enia yi wipe, Bayi li Oluwa wi, Ẹ má gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin wipe, Sa wò o, ohun-èlo ile Oluwa li a o mu pada li aipẹ nisisiyi lati Babeli wá: nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
17Ẹ máṣe gbọ́ ti wọn; ẹ sin ọba Babeli, ẹ si yè: ẽṣe ti ilu yi yio fi di ahoro?
18Ṣugbọn bi nwọn ba ṣe woli, ati bi ọ̀rọ Oluwa ba wà pẹlu wọn, jẹ ki nwọn ki o bẹbẹ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ki ohun-èlo iyokù ni ile Oluwa ati ni ile ọba Judah, ati ni Jerusalemu, ki nwọn ki o máṣe lọ si Babeli.
19Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti opó mejeji, ati niti agbada nla, ati niti ipilẹṣẹ, ati niti ohun-èlo iyokù ti o kù ni ilu yi.
20Eyi ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kò mu lọ nigbati o mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli, pẹlu gbogbo awọn ọlọla Juda ati Jerusalemu;
21Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, niti ohun-èlo ti o kù ni ile Oluwa, ati ni ile ọba Juda ati Jerusalemu.
22A o kó wọn lọ si Babeli, nibẹ ni nwọn o wà titi di ọjọ na ti emi o bẹ̀ wọn wò, li Oluwa wi, emi o si mu wọn goke wá, emi o si mu wọn pada wá si ibi yi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 27: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.