A. Oni 6:11-40

A. Oni 6:11-40 YBCV

Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani. Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara. Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ. OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi? O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi. OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan. On si wi fun u pe, Bi o ba ṣepe mo ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, njẹ fi àmi kan hàn mi pe iwọ bá mi sọ̀rọ. Máṣe lọ kuro nihin, emi bẹ̀ ọ, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, ti emi o si fi mú ọrẹ mi fun ọ wá, ati ti emi o si fi gbé e kalẹ niwaju rẹ. On si wipe, Emi o duro titi iwọ o si fi pada wá. Gideoni si wọ̀ inu ilé lọ, o si pèse ọmọ ewurẹ kan, ati àkara alaiwu ti iyẹfun òṣuwọn efa kan: ẹran na li o fi sinu agbọ̀n, omi rẹ̀ li o si fi sinu ìkoko, o si gbé e jade tọ̀ ọ wá labẹ igi-oaku na, o si gbé e siwaju rẹ̀. Angeli Ọlọrun na si wi fun u pe, Mú ẹran na, ati àkara alaiwu na, ki o si fi wọn lé ori okuta yi, ki o si dà omi ẹran na silẹ. On si ṣe bẹ̃. Nigbana ni angeli OLUWA nà ọpá ti o wà li ọwọ rẹ̀, o si fi ori rẹ̀ kàn ẹran na ati àkara alaiwu na; iná si là lati inu okuta na jade, o si jó ẹran na, ati àkara alaiwu; angeli OLUWA na si lọ kuro niwaju rẹ̀. Gideoni si ri pe angeli OLUWA ni; Gideoni si wipe, Mo gbé, OLUWA Ọlọrun! nitoriti emi ri angeli OLUWA li ojukoju. OLUWA si wi fun u pe, Alafia fun ọ; má ṣe bẹ̀ru: iwọ́ ki yio kú. Nigbana ni Gideoni mọ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jehofa-ṣalomu: o wà ni Ofra ti awọn Abiesri sibẹ̀ titi di oni. O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ: Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun. Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru. Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ. Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi. Nigbana li awọn ọkunrin ilu na wi fun Joaṣi pe, Mú ọmọ rẹ jade wá ki o le kú: nitoripe o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ati nitoriti o bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ. Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli. Ṣugbọn ẹmi OLUWA bà lé Gideoni, on si fun ipè; Abieseri si kójọ sẹhin rẹ̀. On si rán onṣẹ si gbogbo Manasse; awọn si kójọ sẹhin rẹ̀ pẹlu: o si rán onṣẹ si Aṣeri, ati si Sebuluni, ati si Naftali; nwọn si gòke wá lati pade wọn. Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Bi iwọ o ba ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, bi iwọ ti wi, Kiyesi i, emi o fi irun agutan le ilẹ-pakà; bi o ba ṣepe ìri sẹ̀ sara kìki irun nikan, ti gbogbo ilẹ si gbẹ, nigbana li emi o mọ̀ pe iwọ o ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, gẹgẹ bi iwọ ti wi. Bẹ̃li o si ri: nitoriti on dide ni kùtukutu ijọ́ keji, o si fọ́n irun agutan na, o si fọ́n ìri na kuro lara rẹ̀, ọpọ́n kan si kún fun omi. Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Má ṣe jẹ ki ibinu rẹ ki o rú si mi, emi o sọ̀rọ lẹ̃kanṣoṣo yi: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o fi irun na ṣe idanwò lẹ̃kan yi; jẹ ki irun agutan nikan ki o gbẹ, ṣugbọn ki ìri ki o wà lori gbogbo ilẹ. Ọlọrun si ṣe bẹ̃ li oru na: nitoriti irun agutan na gbẹ, ìri si wà lori gbogbo ilẹ na.