AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje.
Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni.
O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá;
Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ.
Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run.
Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA.
O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA nitori awọn Midiani,
OLUWA si rán wolĩ kan si awọn ọmọ Israeli: ẹniti o wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Emi mú nyin gòke ti Egipti wá, mo si mú nyin jade kuro li oko-ẹrú;
Emi si gbà nyin li ọwọ́ awọn ara Egipti, ati li ọwọ́ gbogbo awọn ti npọ́n nyin loju, mo si lé wọn kuro niwaju nyin, mo si fi ilẹ wọn fun nyin;
Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́.
Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani.
Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara.
Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ.
OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi?