A. Oni 11:30-40

A. Oni 11:30-40 YBCV

Jefta si jẹ́ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, o si wi pe, Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ, Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun. Jefta si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni, lati bá wọn jà; OLUWA si fi nwọn lé e lọwọ. On si pa wọn ni ipakupa lati Aroeri lọ, titi dé atiwọ̀ Miniti, ani ogún ilu, titi o fi dé Abeli-kiramimu. Bẹ̃li a ṣẹgun awọn ọmọ Ammoni niwaju awọn ọmọ Israeli. Jefta si bọ̀ si ile rẹ̀ ni Mispa, si kiyesi i, ọmọbinrin rẹ̀ si jade wá ipade rẹ̀ ti on ti timbrili ati ijó: on nikan si li ọmọ rẹ̀; lẹhin rẹ̀ kò ní ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. O si ṣe nigbati o ri i, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Yẽ, ọmọ mi! iwọ rẹ̀ mi silẹ gidigidi, iwọ si li ọkan ninu awọn ti nyọ mi lẹnu: nitori emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada. On si wi fun u pe, Baba mi, iwọ ti yà ẹnu rẹ si OLUWA; ṣe si mi gẹgẹ bi eyiti o ti ẹnu rẹ jade; niwọnbi OLUWA ti gbẹsan fun ọ lara awọn ọtá rẹ, ani lara awọn ọmọ Ammoni. On si wi fun baba rẹ̀ pe, Jẹ ki a ṣe nkan yi fun mi: jọwọ mi jẹ li oṣù meji, ki emi ki o lọ ki emi si sọkalẹ sori òke, ki emi ki o le sọkun nitori ìwa-wundia mi, emi ati awọn ẹgbẹ mi. On si wipe, Lọ. O si rán a lọ niwọn oṣù meji: o si lọ, ati on ati awọn ẹgbẹ rẹ̀, o si sọkun nitori ìwa-wundia rẹ̀ lori òke wọnni. O si ṣe li opin oṣù keji, o si pada wá sọdọ baba rẹ̀, ẹniti o ṣe si i gẹgẹ bi ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́: on kò si mọ̀ ọkunrin. O si di ìlana ni Israeli pe, Ki awọn ọmọbinrin Israeli ma lọ li ọdọdún lati pohunrere ọmọbinrin Jefta ara Gileadi li ọjọ́ mẹrin li ọdún.