Bi a bá si fi ijanu bọ̀ ẹṣin li ẹnu, ki nwọn ki o le gbọ́ ti wa, gbogbo ara wọn li awa si nyi kiri pẹlu. Kiyesi awọn ọkọ̀ pẹlu, bi nwọn ti tobi to nì, ti a si nti ọwọ ẹfũfu lile gbá kiri, itọkọ̀ kekere li a fi ndari wọn kiri, sibikibi ti o bá wù ẹniti ntọ́ ọkọ̀. Bẹ̃ pẹlu li ahọn jẹ ẹ̀ya kekere, o si nfọnnu ohun nla. Wo igi nla ti iná kekere nsun jóna! Iná si ni ahọ́n, aiye ẹ̀ṣẹ si ni: li arin awọn ẹ̀ya ara wa, li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ́ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apãdi si ntinabọ on na. Nitori olukuluku ẹda ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ejò, ati ti ohun ti mbẹ li okun, li a ntù loju, ti a si ti tù loju lati ọwọ ẹda enia wá. Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni. On li awa fi nyìn Oluwa ati Baba, on li a si fi mbú enia, ti a dá li aworan Ọlọrun. Lati ẹnu kanna ni iyìn ati ẽbú ti njade. Ẹnyin ará mi, nkan wọnyi kò yẹ ki o ri bẹ̃. Orisun a ha mã sun omi tutù ati omiró jade lati ojusun kanna wá bi? Ẹnyin ará mi, igi ọpọtọ ha le so eso olifi bi? tabi ajara le so eso ọpọtọ? bẹ̃li orisun kan kò le sun omiró ati omi tutù.
Kà Jak 3
Feti si Jak 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jak 3:3-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò