Jak 2:8-26

Jak 2:8-26 YBCV

Ṣugbọn bi ẹnyin ba nmu olú ofin nì ṣẹ gẹgẹ bi iwe-mimọ́, eyini ni, Iwọ fẹ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ, ẹnyin nṣe daradara. Ṣugbọn bi ẹnyin ba nṣe ojuṣãju enia, ẹnyin ndẹ̀ṣẹ, a si nda nyin lẹbi nipa ofin bi arufin. Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ́, ti o si rú ọ̀kan, o jẹbi gbogbo rẹ̀. Nitori ẹniti o wipe, Máṣe ṣe panṣaga, on li o si wipe, Máṣe pania. Njẹ bi iwọ kò ṣe panṣaga, ṣugbọn ti iwọ pania, iwọ di arufin. Ẹ mã sọrọ bẹ̃, ẹ si mã huwa bẹ̃, bi awọn ti a o fi ofin omnira dá li ẹjọ. Nitori ẹniti kò ṣãnu, li a o ṣe idajọ fun laisi ãnu; ãnu nṣogo lori idajọ. Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi? Bi arakunrin tabi arabinrin kan ba wà ni ìhoho, ti o si ṣe aili onjẹ õjọ, Ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ? Bẹ̃ si ni igbagbọ́, bi kò ba ni iṣẹ, o kú ninu ara. Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi. Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri. Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni? Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ? Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé. Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Njẹ ẹnyin ri pe nipa iṣẹ li a ndá enia lare, kì iṣe nipa igbagbọ́ nikan. Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran? Nitori bi ara li aisi ẹmí ti jẹ́ okú, bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni igbagbọ́ li aisi iṣẹ jẹ́ okú.