Ẹ ba Jerusalemu yọ̀, ki inu nyin si dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹnyin ti o fẹ ẹ; ẹ ba a yọ̀ fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti ngbãwẹ̀ fun u. Ki ẹnyin ki o le mu ọmú, ki a si fi ọmú itunu rẹ̀ tẹ́ nyin lọrùn; ki ẹnyin ki o ba le fun wàra, ki inu nyin ba sì le dùn si ọ̀pọlọpọ ogo rẹ̀. Nitori bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o nà alafia si i bi odò, ati ogo awọn Keferi bi odò ṣiṣàn: nigbana li ẹnyin o mu ọmú, a o dà nyin si ẹgbẹ́ rẹ̀, a o si ma gbe nyin jo lori ẽkún rẹ̀. Gẹgẹ bi ẹniti iya rẹ̀ ntù ninu, bẹ̃ni emi o tù nyin ninu; a o si tù nyin ninu ni Jerusalemu.
Kà Isa 66
Feti si Isa 66
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 66:10-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò