Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo. Nwọn o si mọ ibi ahoro atijọ wọnni, nwọn o gbe ahoro atijọ wọnni ro, nwọn o si tun ilu wọnni ti o ṣofo ṣe, ahoro iran ọ̀pọlọpọ. Awọn alejò yio si duro, nwọn o si bọ́ ọwọ́ ẹran nyin, awọn ọmọ alejò yio si ṣe atulẹ nyin, ati olurẹ́ ọwọ́ àjara nyin. Ṣugbọn a o ma pè nyin ni Alufa Oluwa: nwọn o ma pè nyin ni Iranṣẹ Ọlọrun wa: ẹ o jẹ ọrọ̀ awọn Keferi, ati ninu ogo wọn li ẹ o mã ṣogo. Nipo itijú nyin ẹ o ni iṣẹpo-meji; ati nipo idãmu, nwọn o yọ̀ ninu ipin wọn: nitorina nwọn o ni iṣẹpo-meji ni ilẹ wọn: ayọ̀ ainipẹkun yio jẹ ti wọn.
Kà Isa 61
Feti si Isa 61
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 61:3-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò