DIDE, tàn imọlẹ: nitori imọlẹ rẹ dé, ogo Oluwa si yọ lara rẹ. Nitori kiyesi i, okùnkun bò aiye mọlẹ, ati okùnkun biribiri bò awọn enia: ṣugbọn Oluwa yio yọ lara rẹ, a o si ri ogo rẹ̀ lara rẹ. Awọn keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ. Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ. Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ.
Kà Isa 60
Feti si Isa 60
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 60:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò