Isa 60

60
Ògo Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu
1DIDE, tàn imọlẹ: nitori imọlẹ rẹ dé, ogo Oluwa si yọ lara rẹ.
2Nitori kiyesi i, okùnkun bò aiye mọlẹ, ati okùnkun biribiri bò awọn enia: ṣugbọn Oluwa yio yọ lara rẹ, a o si ri ogo rẹ̀ lara rẹ.
3Awọn keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ.
4Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ.
5Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ.
6Ọ̀pọlọpọ rakunmi yio bò ọ mọlẹ, awọn ọmọ rakunmi Midiani on Ẹfa; gbogbo wọn o wá lati Ṣeba: nwọn o mu wura ati turari wá; nwọn o fi iyìn Oluwa hàn sode.
7A o ṣà gbogbo ọwọ́-ẹran Kedari jọ sọdọ rẹ, awọn àgbo Nebaioti yio ṣe iranṣẹ fun ọ; nwọn o goke wá si pẹpẹ mi pẹlu itẹwọgba, emi o si ṣe ile ogo mi li ogo.
8Tani wọnyi ti nfò bi awọsanma, ati bi awọn ẹiyẹle si ojule wọn?
9Nitõtọ erekuṣu wọnni yio duro dè mi, ọkọ Tarṣiṣi wọnni li ekini, lati mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti ọ̀na jìjin wá, fadaka wọn, ati wura wọn pẹlu wọn, fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ, ati fun Ẹni-Mimọ́ Israeli, nitoriti on ti ṣe ọ logo.
10Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ìkannu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣãnu fun ọ.
11Nitori na awọn ẹnu-bodè rẹ yio ṣi silẹ nigbagbogbo; a kì yio se wọn lọsan tabi loru, ki a le mu ọla awọn Keferi wá sọdọ rẹ, ki a ba si mu awọn ọba wọn wá.
12Nitori orilẹ-ède, tabi ilẹ ọba ti kì yio sin ọ, yio ṣegbe; orilẹ-ède wọnni li a o sọ dahoro raurau.
13Ogo Lebanoni yio wá sọdọ rẹ, igi firi, igi pine, pẹlu igi boksi, lati ṣe ibi mimọ́ mi li ọṣọ; emi o ṣe ibi ẹsẹ mi logo.
14Awọn ọmọkunrin awọn aninilara rẹ pẹlu yio wá ni itẹriba sọdọ rẹ; gbogbo awọn ti o ti ngàn ọ, nwọn o tẹ̀ ara wọn ba silẹ li atẹlẹsẹ rẹ; nwọn o si pe ọ ni Ilu Oluwa, Sioni ti Ẹni-Mimọ́ Israeli.
15Ni bi a ti kọ̀ ọ silẹ, ti a si ti korira rẹ, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja lãrin rẹ, emi o sọ ọ di ogo aiyeraiye, ayọ̀ iran-de-iran ọ̀pọlọpọ.
16Iwọ o mu wàra awọn Keferi, iwọ o si mu ọmu awọn ọba; iwọ o si mọ̀ pe, emi Oluwa ni Olugbala rẹ, ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara Jakobu.
17Nipo idẹ emi o mu wura wá, nipo irin emi o mu fadaka wá, ati nipo igi, idẹ, ati nipo okuta, irin: emi o ṣe awọn ijoye rẹ ni alafia, ati awọn akoniṣiṣẹ́ rẹ ni ododo.
18A kì yio gbọ́ ìwa-ipá mọ ni ilẹ rẹ, idahoro tabi iparun li agbègbe rẹ; ṣugbọn iwọ o pe odi rẹ ni Igbala, ati ẹnu-bodè rẹ ni Iyin.
19Õrùn kì yio jẹ imọlẹ rẹ mọ li ọsan, bẹ̃ni oṣupa kì yio fi imọlẹ rẹ̀ ràn fun ọ; ṣugbọn Oluwa yio ṣe imọlẹ ainipẹkun rẹ, ati Ọlọrun rẹ ogo rẹ.
20Õrùn rẹ ki yio wọ̀ mọ; bẹ̃ni oṣupa rẹ kì yio wọ̃kùn: nitori Oluwa yio jẹ imọlẹ ainipẹkun fun ọ, ọjọ ãwẹ̀ rẹ wọnni yio si de opin.
21Ati awọn enia rẹ, gbogbo wọn o jẹ olododo: nwọn o jogun ilẹ na titi lailai, ẹka gbigbin mi, iṣẹ ọwọ́ mi, ki a ba le yìn mi logo.
22Ẹni-kekere kan ni yio di ẹgbẹrun, ati kekere kan yio di alagbara orilẹ-ède: emi Oluwa yio ṣe e kankan li akokò rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 60: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀