Isa 57
57
OLUWA dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli Lẹ́bi
1OLODODO ṣegbe, kò si ẹniti o kà a si: a mu awọn alãnu kuro, kò si ẹniti nrò pe a mu olododo kuro ṣaju ibi.
2On wọ̀ inu alafia: nwọn simi lori akete wọn, olukuluku ẹniti nrin ninu iduroṣinṣin rẹ̀.
3Ṣugbọn ẹ sunmọ ihin, ẹnyin ọmọ oṣo, iru-ọmọ panṣaga on àgbere.
4Tani ẹnyin fi nṣe ẹsín? tani ẹnyin nyanu gborò si, ti ẹnyin yọ ahọn jade si? ọmọ alarekọja ki ẹnyin, iru-ọmọ eke,
5Ti òriṣa ngùn labẹ gbogbo igi tutù, ti ẹ npa awọn ọmọ wẹrẹ ninu afonifoji wọnni, labẹ apáta ti o yanu?
6Lãrin okuta ọ̀bọrọ́ odo ni ipín rẹ, awọn, awọn ni ipín rẹ: ani awọn ni iwọ dà ẹbọ ọrẹ mimu si: ti iwọ si rú ẹbọ ọrẹ jijẹ. Emi ha le gbà itunu ninu wọnyi?
7Lori oke giga giga ni iwọ fi akete rẹ si, ani nibẹ ni iwọ ti lọ lati rú ẹbọ.
8Lẹhin ilẹkùn ati opó ilẹkun ni iwọ si ti gbe iranti rẹ soke: nitori iwọ ti fi ara rẹ hàn fun ẹlomiran dipò mi, iwọ si ti goke: iwọ ti sọ akete rẹ di nla, iwọ si ba wọn dá majẹmu; iwọ ti fẹ akete wọn nibiti iwọ ri i.
9Iwọ si ti lọ tiwọ ti ikunra sọdọ ọba, iwọ si ti sọ õrùn didùn rẹ di pupọ, iwọ si ti rán awọn ikọ̀ rẹ lọ jina réré, iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ, ani si ipò okú.
10Ãrẹ̀ mu ọ ninu jijìn ọ̀na rẹ: iwọ kò wipe, Ireti kò si: ìye ọwọ́ rẹ ni iwọ ti ri; nitorina ni inu rẹ kò ṣe bajẹ.
11Ẹ̀ru tani mbà ọ ti o si nfòya, ti o nṣeke, ti iwọ kò si ranti mi tabi ki o kà a si? emi kò ha ti dakẹ ani lati igbãni wá, iwọ kò si bẹ̀ru mi?
12Emi o fi ododo rẹ, ati iṣẹ rẹ hàn; nwọn kì o si gbè ọ.
13Nigbati iwọ ba kigbe, jẹ ki awọn ẹgbẹ rẹ ki o gbà ọ; ṣugbọn ẹfũfu ni yio gbá gbogbo wọn lọ; emi yio mu wọn kuro: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹ rẹ̀ le mi yio ni ilẹ na, yio si jogun oke mimọ́ mi.
Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn
14On o si wipe, Ẹ kọ bèbe, ẹ kọ bèbe, ẹ tun ọ̀na ṣe; ẹ mu ìdugbolu kuro li ọ̀na awọn enia mi.
15Nitori bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti a gbéga soke sọ, ti ngbe aiyeraiye, orukọ ẹniti ijẹ Mimọ́, emi ngbe ibi giga ati mimọ́, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji.
16Nitori emi kì yio jà titi lai, bẹ̃ni emi kì yio binu nigbagbogbo: nitori ẹmi iba daku niwaju mi, ati ẽmi ti emi ti dá.
17Mo ti binu nitori aiṣedede ojukokoro rẹ̀, mo si lù u: mo fi oju pamọ́, mo si binu, on si nlọ ni iṣìna li ọ̀na ọkàn rẹ̀.
18Mo ti ri ọ̀na rẹ̀, emi o si mu u li ara da: emi o si tọ́ ọ pẹlu, emi o si mu itunu pada fun u wá, ati fun awọn aṣọ̀fọ rẹ̀.
19Emi li o da eso ète; Alafia, alafia fun ẹniti o jina rére, ati fun ẹniti o wà nitosí, ni Oluwa wi; emi o si mu u li ara da.
20Ṣugbọn awọn enia buburu dabi okun ríru, nigbati kò le simi, eyiti omi rẹ̀ nsọ ẹrẹ ati ẽri soke.
21Alafia kò si fun awọn enia buburu, ni Ọlọrun mi wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 57: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.