Nitori nigbati mo de, kò si ẹnikan? nigbati mo pè, kò si ẹnikan lati dahùn? Ọwọ́ mi ha kuru tobẹ̃ ti kò fi le rapada? tabi emi kò ha li agbara lati gbani? Kiyesi i, ni ibawi mi mo gbẹ okun, mo sọ odò nla di aginjù, ẹja wọn nrùn nitori ti omi kò si, nwọn si kú fun ongbẹ. Mo fi ohun dúdu wọ̀ awọn ọrun, mo si fi aṣọ ọfọ̀ ṣe ibora wọn. Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ. Oluwa Jehofa ti ṣí mi li eti, emi kò si ṣe aigbọràn, bẹ̃ni emi kò yipada.
Kà Isa 50
Feti si Isa 50
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 50:2-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò