Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò! Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn! Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile: Awọn ẹniti o da are fun ẹni-buburu nitori ère, ti nwọn si mu ododo olododo kuro li ọwọ́ rẹ̀. Nitorina bi iná ti ijo akekù koriko run, ti ọwọ́ iná si ijo iyàngbo; bẹ̃ni egbò wọn yio da bi rirà; itanna wọn yio si gòke bi ekuru; nitori nwọn ti ṣá ofin Oluwa awọn ọmọ-ogun tì, nwọn si ti gàn ọ̀rọ Ẹni-Mimọ Israeli.
Kà Isa 5
Feti si Isa 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 5:20-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò