Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo. Awọn ọmọ rẹ yára; awọn oluparun rẹ ati awọn ti o fi ọ ṣofò yio ti ọdọ rẹ jade. Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo.
Kà Isa 49
Feti si Isa 49
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 49:15-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò