Isa 44:9-20

Isa 44:9-20 YBCV

Asan ni gbogbo awọn ti ngbẹ ere; nkan iyebiye wọn ki yio si lerè; awọn tikala wọn li ẹlẹri ara wọn: nwọn kò riran, bẹ̃ni nwọn kò mọ̀; ki oju ba le tì wọn. Tani yio gbẹ́ oriṣa, tabi ti yio dà ere ti kò ni ère kan? Kiyesi i, oju o tì gbogbo awọn ẹgbẹ́ rẹ̀; awọn oniṣọna, enia ni nwọn: jẹ ki gbogbo wọn kò ara wọn jọ, ki nwọn dide duro; nwọn o bẹ̀ru, oju o si jumọ tì wọn. Alagbẹdẹ rọ ãke kan, o ṣiṣẹ ninu ẹyín, o fi ọmọ-owú rọ ọ, o si fi agbara apá rẹ̀ ṣe e: ebi npa a pẹlu, agbara rẹ̀ si tan; ko mu omi, o si rẹ̀ ẹ. Gbẹnàgbẹnà ta okùn rẹ̀, o si fi nkan pupa sàmi rẹ̀, o fi ìfá fá a, o si fi kọmpassi là a birikiti: o sì yá a li aworán ọkunrin, gẹgẹ bi ẹwà enia, ki o le ma gbe inu ile. O bẹ́ igi kedari lu ilẹ fun ra rẹ̀, o si mu igi kipressi ati oaku, o si mu u le fun ra rẹ̀ ninu awọn igi igbó: o gbìn igi aṣi, ojò si mu u dagba. Nigbana ni yio jẹ ohun idana fun enia: nitori yio mu ninu wọn, yio si fi yá iná; lõtọ, o dá iná, o si din akara, lõtọ, o ṣe ọlọrun fun ra rẹ̀, o si nsìn i; o gbẹ ẹ li ere, o si nforibalẹ fun u. Apakan ninu rẹ̀ li o fi dá iná, apakan ninu rẹ̀ li o fi jẹ ẹran: o sun sisun, o si yo, o yá iná pẹlu, o si wipe, Ahã, ara mi gbona, mo ti ri iná. Iyokù rẹ̀ li o si fi ṣe ọlọrun, ani ere gbigbẹ́ rẹ̀, o foribalẹ fun u, o sìn i, o gbadura si i, o si wipe, Gbà mi; nitori iwọ li ọlọrun mi. Nwọn kò mọ̀, oye ko si ye wọn: nitori o dí wọn li oju, ki nwọn ki o má le ri; ati aiya wọn, ki oye ki o má le ye wọn. Kò si ẹniti o rò li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni ko si imọ̀ tabi oye lati wipe, Mo ti fi apakan rẹ̀ da iná; mo si din akara pẹlu lori ẹyin iná rẹ̀: mo ti sun ẹran, mo si jẹ ẹ: emi o ha fi iyokù rẹ̀ ṣe irira? emi o ha foribalẹ fun ìti igi? O fi ẽru bọ́ ara rẹ̀: aiya ẹtàn ti dari rẹ̀ si apakan, ti kò le gbà ọkàn rẹ̀ là, bẹ̃ni kò le wipe, Eke ko ha wà li ọwọ́ ọtun mi?