Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀: Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi. Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu. Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́.
Kà Isa 42
Feti si Isa 42
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 42:5-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò