Isa 35
35
Ọ̀nà Ìwà Mímọ́
1AGINJU ati ilẹ gbigbẹ yio yọ̀ fun wọn; ijù yio yọ̀, yio si tanna bi lili.
2Ni titanna yio tanna; yio si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni li a o fi fun u, ẹwà Karmeli on Ṣaroni; nwọn o ri ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa.
3Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun.
4Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin.
5Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi.
6Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.
7Ilẹ yíyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi; ni ibugbé awọn dragoni, nibiti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ ọgbà fun ẽsú on iyè.
8Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i.
9Kiniun kì yio si nibẹ, bẹ̃ni ẹranko buburu kì yio gùn u, a kì yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rìn nibẹ:
10Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 35: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.