EGBÉ ni fun iwọ abanijẹ, ti a kò si bà ọ jẹ: ti o nhùwa arekereke, ti a kò si hùwa arekereke si ọ! nigbati iwọ o dẹkun ati banijẹ, a o bà ọ jẹ; ati nigbati iwọ bá fi opin si ihùwa arekereke, nwọn o hùwa arekereke si ọ.
Oluwa, ṣãnu fun wa; awa ti duro dè ọ: iwọ mã ṣe apá wọn li òròwúrọ̀ ani igbala wa nigba ipọnju.
Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká.
A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn.
Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni.
On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀.
Kiyesi i, awọn akọni kigbe lode, awọn ikọ̀ alafia sọkún kikorò.
Ọ̀na opopo nla wọnni ṣófo, èro dá, on ti bà majẹmu jẹ, o ti kẹgàn ilu wọnni, kò kà ẹnikan si.
Ilẹ ngbawẹ̀ o si njoro, oju ntì Lebanoni o si rọ: Ṣaroni dabi aginju; ati Baṣani ati Karmeli gbọ̀n eso wọn danù.
Oluwa wipe, nisisiyi li emi o dide, nisisiyi li emi o gbe ara mi soke.
Ẹ o loyun iyangbò, ẹ o si bi pòropóro; ẽmi nyin, bi iná, yio jẹ nyin run.
Awọn enia yio si dabi sisun ẽru, bi ẹgún ti a ké ni nwọn o jo ninu iná.
Ẹ gbọ́, ẹnyin ti o jìna rére, eyi ti mo ti ṣe; ati ẹnyin ti o sunmọ tosí, ẹ jẹwọ agbara mi.
Ẹ̀ru bà awọn ẹlẹṣẹ̀ ni Sioni; ibẹru-bojo ti mu awọn agabàgebè. Tani ninu wa ti o le gbe inu ajonirun iná? tani ninu wa ti yio le gbe inu iná ainipẹkun?
Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi.
On na yio gbe ibi giga: ile apáta yio ṣe ibi ãbo rẹ̀: a o fi onjẹ fun u; omi rẹ̀ yio si daju.