Isa 33
33
Adura fún Ìrànlọ́wọ́
1EGBÉ ni fun iwọ abanijẹ, ti a kò si bà ọ jẹ: ti o nhùwa arekereke, ti a kò si hùwa arekereke si ọ! nigbati iwọ o dẹkun ati banijẹ, a o bà ọ jẹ; ati nigbati iwọ bá fi opin si ihùwa arekereke, nwọn o hùwa arekereke si ọ.
2Oluwa, ṣãnu fun wa; awa ti duro dè ọ: iwọ mã ṣe apá wọn li òròwúrọ̀ ani igbala wa nigba ipọnju.
3Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká.
4A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn.
5Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni.
6On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀.
7Kiyesi i, awọn akọni kigbe lode, awọn ikọ̀ alafia sọkún kikorò.
8Ọ̀na opopo nla wọnni ṣófo, èro dá, on ti bà majẹmu jẹ, o ti kẹgàn ilu wọnni, kò kà ẹnikan si.
9Ilẹ ngbawẹ̀ o si njoro, oju ntì Lebanoni o si rọ: Ṣaroni dabi aginju; ati Baṣani ati Karmeli gbọ̀n eso wọn danù.
OLUWA Kìlọ̀ fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀
10Oluwa wipe, nisisiyi li emi o dide, nisisiyi li emi o gbe ara mi soke.
11Ẹ o loyun iyangbò, ẹ o si bi pòropóro; ẽmi nyin, bi iná, yio jẹ nyin run.
12Awọn enia yio si dabi sisun ẽru, bi ẹgún ti a ké ni nwọn o jo ninu iná.
13Ẹ gbọ́, ẹnyin ti o jìna rére, eyi ti mo ti ṣe; ati ẹnyin ti o sunmọ tosí, ẹ jẹwọ agbara mi.
14Ẹ̀ru bà awọn ẹlẹṣẹ̀ ni Sioni; ibẹru-bojo ti mu awọn agabàgebè. Tani ninu wa ti o le gbe inu ajonirun iná? tani ninu wa ti yio le gbe inu iná ainipẹkun?
15Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi.
16On na yio gbe ibi giga: ile apáta yio ṣe ibi ãbo rẹ̀: a o fi onjẹ fun u; omi rẹ̀ yio si daju.
Ọjọ́ Ọ̀la tó Lógo
17Oju rẹ̀ yio ri ọba ninu ẹwà rẹ̀: nwọn o ma wò ilẹ ti o jina réré.
18Aiyà rẹ yio ṣe aṣaro ẹ̀ru nla. Nibo ni akọwe wà? nibo ni ẹniti nwọ̀n nkan gbe wà? nibo ni ẹniti o nkà ile-ẹ̀ṣọ wọnni gbe wà?
19Iwọ kì yio ri awọn enia ti o muná; awọn enia ti ọ̀rọ wọn jinlẹ jù eyiti iwọ le gbọ́, ti ahọn wọn ṣe ololò, ti kò le ye ọ.
20Wo Sioni, ilu ajọ afiyesi wa: oju rẹ yio ri Jerusalemu ibugbe idakẹjẹ, agọ́ ti a kì yio tú palẹ mọ; kò si ọkan ninu ẽkàn rẹ ti a o ṣí ni ipò lai, bẹ̃ni kì yio si ọkan ninu okùn rẹ̀ ti yio já.
21Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja.
22Nitori Oluwa ni onidajọ wa, Oluwa li olofin wa, Oluwa li ọba wa; on o gbà wa là.
23Okùn opó-ọkọ̀ rẹ tú; nwọn kò le dì opó-ọkọ̀ mu le danin-danin, nwọn kò le ta igbokun: nigbana li a pin ikogun nla; amúkun ko ikogun.
24Ati awọn ará ibẹ̀ ki yio wipe, Ara mi kò yá: a o dari aiṣedede awọn enia ti ngbe ibẹ jì wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 33: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.