Isa 22

22
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu
1Ọ̀RỌ-ìmọ niti afonifoji ojuran. Kili o ṣe ọ nisisiyi, ti iwọ fi gùn ori ile lọ patapata?
2Iwọ ti o kún fun ìrukerudo, ilu aitòro, ilu ayọ̀: a kò fi idà pa awọn okú rẹ, bẹ̃ni nwọn kò kú li ogun.
3Gbogbo awọn alakoso rẹ ti jumọ sa lọ, awọn tafàtafà ti dì wọn ni igbekun: gbogbo awọn ti a ri ninu rẹ li a dì jọ, ti o ti sa lati okere wá.
4Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi.
5Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla.
6Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ.
7Yio si ṣe, afonifoji àṣayan rẹ yio kún fun kẹkẹ́, awọn ẹlẹṣin yio si tẹ́ ogun niha ẹnu odi.
8On si ri iboju Juda, iwọ si wò li ọjọ na ihamọra ile igbó.
9Ẹnyin ti ri oju-iho ilu Dafidi pẹlu, pe, nwọn pọ̀: ẹnyin si gbá omi ikudu isalẹ jọ.
10Ẹnyin ti kà iye ile Jerusalemu, awọn ile na li ẹnyin biwó lati mu odi le.
11Ẹnyin pẹlu ti wà yàra lãrin odi meji fun omi ikudu atijọ: ṣugbọn ẹnyin kò wò ẹniti o ṣe e, bẹ̃ni ẹ kò si buyìn fun ẹniti o ṣe e nigbãni,
12Ati li ọjọ na ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio pè lati sọkun, ati lati ṣọ̀fọ, ati lati fá ori, ati lati sán aṣọ ọ̀fọ.
13Si kiyesi i, ayọ̀ ati inu-didùn, pipa malũ, ati pipa agutan, jijẹ ẹran, ati mimu ọti-waini: ẹ jẹ ki a ma jẹ, ki a si ma mu; nitori ọla li awa o kú.
14Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ li eti mi, pe, Nitõtọ, a kì yio fọ̀ aiṣedede yi kuro lara nyin titi ẹnyin o fi kú, li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Ìkìlọ̀ fún Ṣebna
15Bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Lọ, tọ olutọju yi lọ, ani tọ Ṣebna lọ, ti iṣe olori ile,
16Si wipe, Kili o ni nihin? ati tali o ni nihin, ti iwọ fi wà ibojì nihin bi ẹniti o wà ibojì fun ara rẹ̀ nibi giga, ti o si gbẹ́ ibugbé fun ara rẹ̀ ninu apáta?
17Kiyesi i, Oluwa yio fi sisọ agbara sọ ọ nù, yio si bò ọ mọlẹ.
18Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ.
19Emi o si le ọ jade kuro ni ibujoko rẹ, yio tilẹ wọ́ ọ kuro ni ipò rẹ.
20Yio si ṣe li ọjọ na, ni emi o pè Eliakimu iranṣẹ mi ọmọ Hilkiah.
21Emi o si fi aṣọ-igunwà rẹ wọ̀ ọ, emi o si fi àmure rẹ dì i, emi o si fi ijọba rẹ le e li ọwọ́: on o si jẹ baba fun awọn olugbé Jerusalemu, ati fun ile Juda.
22Iṣikà ile Dafidi li emi o fi le èjiká rẹ̀: yio si ṣí, kò si ẹniti yio tì; on o si tì, kò si si ẹniti yio ṣí.
23Emi o si kàn a bi iṣó ni ibi ti o le, on o jẹ fun itẹ ogo fun ile baba rẹ̀.
24Gbogbo ogo ile baba rẹ̀ ni nwọn o si fi kọ́ ọ li ọrùn, ati ọmọ ati eso, gbogbo ohun-elò ife titi de ago ọti.
25Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Li ọjọ na, ni a o ṣi iṣó ti a kàn mọ ibi ti o le ni ipò, a o si ke e lu ilẹ, yio si ṣubu; ẹrù ara rẹ̀ li a o ké kuro: nitori Oluwa ti sọ ọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀