Isa 10
10
1EGBE ni fun awọn ti npaṣẹ aiṣododo, ati fun awọn akọwe ti nkọ iwe ìka;
2Lati yi alaini kuro ni idajọ, ati lati mu ohun ẹtọ kuro lọwọ talakà enia mi, ki awọn opo ba le di ijẹ wọn, ati ki wọn ba le jà alainibaba li ole!
3Kili ẹnyin o ṣe lọjọ ibẹ̀wo, ati ni idahoro ti yio ti okere wá? tali ẹnyin o sá tọ̀ fun irànlọwọ? nibo li ẹnyin o si fi ogo nyin si?
4Laisi emi nwọn o tẹ̀ ba labẹ awọn ara-tubu, nwọn o si ṣubu labẹ awọn ti a pa. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Asiria ṣe Àṣejù
5Egbe ni fun Assuri, ọgọ ibinu mi, ati ọ̀pa ọwọ́ wọn ni irúnu mi.
6Emi o ran a si orilẹ-ède agabàgebe, ati fun awọn enia ibinu mi li emi o paṣẹ kan, lati ko ikogun, ati lati mu ohun ọdẹ, ati lati tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ni igboro.
7Ṣugbọn on kò rò bẹ̃, bẹ̃ni ọkàn rẹ̀ kò rò bẹ̃; ṣugbọn o wà li ọkàn rẹ̀ lati parun ati lati ke orilẹ-ède kuro, ki iṣe diẹ.
8Nitori o wipe, Ọba kọ awọn ọmọ-alade mi ha jẹ patapata?
9Kalno kò ha dabi Karkemiṣi? Hamati kò ha dabi Arpadi? Samaria kò ha dabi Damasku?
10Gẹgẹ bi ọwọ́ mi ti nà de ijọba ere ri, ere eyi ti o jù ti Jerusalemu ati ti Samaria lọ.
11Bi emi ti ṣe si Samaria ati ere rẹ̀, emi kì yio ha ṣe bẹ̃ si Jerusalemu ati ere rẹ̀ bi?
12Nitorina yio si ṣe, nigbati Oluwa ti ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀ lori òke Sioni ati Jerusalemu, emi o ba eso aiya lile ọba Assiria wi, ati ogo ìwo giga rẹ̀.
13Nitori o wipe, nipa agbara ọwọ́ mi ni emi ti ṣe e, ati nipa ọgbọ́n mi; nitori emi moye, emi si ti mu àla awọn enia kuro, emi si ti ji iṣura wọn, emi si ti sọ awọn ará ilu na kalẹ bi alagbara ọkunrin.
14Ọwọ́ mi si ti wá ọrọ̀ awọn enia ri bi itẹ ẹiyẹ: ati gẹgẹ bi ẹnipe ẹnikan nko ẹyin ti o kù, li emi ti kó gbogbo aiye jọ; kò si ẹniti o gbọ̀n iyẹ, tabi ti o ya ẹnu, tabi ti o dún.
15Ãke ha le fọnnu si ẹniti nfi i la igi? tabi ayùn ha le gbe ara rẹ̀ ga si ẹniti nmì i? bi ẹnipe ọgọ le mì ara rẹ̀ si awọn ti o gbe e soke, tabi bi ẹnipe ọpa le gbe ara rẹ̀ soke, bi ẹnipe ki iṣe igi.
16Nitorina ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio mu awọn tirẹ̀ ti o sanra di rirù: ati labẹ ogo rẹ̀ yio da jijo kan bi jijo iná.
17Imọlẹ Israeli yio si jẹ iná, ati Ẹni-Mimọ́ rẹ̀ yio jẹ ọwọ́-iná: yio si jo ẹgún ati ẹwọn rẹ̀ run, li ọjọ kan;
18Yio si jo ogo igbó rẹ̀ run, ati oko rẹ̀ ẹlẹtù loju, ati ọkàn ati ara: nwọn o si dabi igbati ọlọpagun ndakú.
19Iyokù igi igbó rẹ̀ yio si jẹ diẹ, ti ọmọde yio le kọwe wọn.
Àwọn Díẹ̀ Yóo Pada Wá
20Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ.
21Awọn iyokù yio pada, awọn iyokù ti Jakobu, si Ọlọrun alagbara.
22Bi Israeli enia rẹ ba dàbi iyanrìn okun, sibẹ iyokù ninu wọn o pada: aṣẹ iparun na yio kun àkúnwọ́sílẹ̀ ninu ododo.
23Nitori Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe iparun, ani ipinnu, li ãrin ilẹ gbogbo.
OLUWA Yóo Jẹ Asiria Níyà
24Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti.
25Ṣugbọn niwọn igba diẹ kiun, irunú yio si tan, ati ibinu mi ninu iparun wọn.
26Oluwa awọn ọmọ-ogun yio gbe paṣan kan soke fun u, gẹgẹ bi ipakupa ti Midiani ni apata Orebu: ati gẹgẹ bi ọgọ rẹ̀ soju okun, bẹ̃ni yio gbe e soke gẹgẹ bi iru ti Egipti.
27Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbe ẹrù rẹ̀ kuro li ejika rẹ, ati àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ, a o si ba àjaga na jẹ ní ọrùn rẹ.
Ọ̀tá Kọlu Jerusalẹmu
28On de si Aiati, on ti kọja si Migroni; ni Mikmaṣi li on ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ si:
29Nwọn ti rekọja ọ̀na na: nwọn ti wọ̀ ni Geba; Rama bẹ̀ru; Gibea ti Saulu sá.
30Gbe ohùn rẹ soke, ọmọbinrin Gallimu: mu ki a gbọ́ ọ de Laiṣi, otòṣi Anatoti.
31A ṣi Madmena nipo dà; awọn ara Gebimu ko ara wọn jọ lati sa.
32Yio duro sibẹ ni Nobu li ọjọ na: on o si mì ọwọ́ rẹ̀ si oke giga ọmọbinrin Sioni, oke kekere Jerusalemu.
33Kiyesi i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio fi ẹ̀ru wọ́n ẹka: ati awọn ti o ga ni inà li a o ke kuro, ati awọn agberaga li a o rẹ̀ silẹ.
34On o si fi irin ke pantiri igbó lu ilẹ, Lebanoni yio si ṣubu nipa alagbara kan.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 10: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.