Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi. Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu. A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn.
Kà Isa 1
Feti si Isa 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 1:2-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò