Hos 7
7
1NIGBATI emi iba mu Israeli li ara dá, nigbana ni ẹ̀ṣẹ Efraimu fi ara hàn, ati ìwa-buburu Samaria; nitori nwọn ṣeké; olè si wọle, ọwọ́ olè si nkoni lode.
2Nwọn kò si rò li ọkàn wọn pe, emi ranti gbogbo ìwa-buburu wọn: nisisiyi iṣẹ ara wọn duro yi wọn ka; nwọn wà niwaju mi.
Ọ̀tẹ̀ ní Ààfin
3Nwọn fi ìwa-buburu wọn mu ki ọba yọ̀; nwọn si fi eké wọn mu awọn ọmọ-alade yọ̀.
4Gbogbo nwọn ni panṣagà, bi ãrò ti alakàra mu gboná, ti o dawọ́ kikoná duro, lẹhìn igbati o ti pò iyẹ̀fun tan, titi yio fi wú.
5Li ọjọ ọba wa, awọn ọmọ-alade ti fi oru ọti-waini mu u ṣaisàn; o nà ọwọ́ rẹ̀ jade pẹlu awọn ẹlẹgàn.
6Nitori nwọn ti mura ọkàn wọn silẹ bi ãrò, nigbati nwọn ba ni buba: alakàra wọn sùn ni gbogbo oru; li owurọ̀ o jo bi ọwọ́-iná.
7Gbogbo wọn gboná bi ãrò, nwọn ti jẹ awọn onidajọ wọn run; gbogbo ọba wọn ṣubu: kò si ẹnikan ninu wọn ti o ke pè mi.
Israẹli ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè
8Efraimu, on ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn enia na; Efraimu ni akàra ti a kò yipadà.
9Awọn alejò ti jẹ agbara rẹ̀ run, on kò si mọ̀: nitõtọ, ewú wà kakiri li ara rẹ̀, sibẹ̀ on kò mọ̀.
10Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a.
11Efraimu pẹlu dabi òpe adàba ti kò li ọkàn; nwọn kọ si Egipti, nwọn lọ si Assiria.
12Nigbati nwọn o lọ, emi o nà àwọn mi le wọn; emi o mu wọn wá ilẹ bi ẹiyẹ oju-ọrun; emi o nà wọn, bi ijọ-enia wọn ti gbọ́.
13Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi.
14Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi.
15Bi mo ti dì, ti mo si fun apa wọn li okun, sibẹ̀ nwọn nrò ibi si mi.
16Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Hos 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.