Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa. Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara, Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye? Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà.
Kà Heb 9
Feti si Heb 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 9:12-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò