NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun: Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia. Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ. Nisisiyi ibaṣepe o mbẹ li aiye, on kì bá tilẹ jẹ alufa, nitori awọn ti nfi ẹbun rubọ gẹgẹ bi ofin mbẹ: Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke. Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹ̃ lọ.
Kà Heb 8
Feti si Heb 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 8:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò