Awa si fẹ ki olukuluku nyin ki o mã fi irú aisimi kanna hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin: Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri. Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ̀ bura, wipe, Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i. Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà. Nitori enia a mã fi ẹniti o pọjù wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹ ọ̀rọ. Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn. Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu: Eyiti awa ni bi idakọ̀ro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin, ti o si wọ̀ inu ile lọ lẹhin aṣọ ikele; Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.
Kà Heb 6
Feti si Heb 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 6:11-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò