NITORI olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mã mu ẹ̀bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ: Ẹniti o le bá awọn alaimoye ati awọn ti o ti yapa kẹdun, nitori a fi ailera yi on na ká pẹlu. Nitori idi eyi li o si ṣe yẹ, bi o ti nṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, bẹ̃ pẹlu ni ki o ṣe fun ara rẹ̀. Kò si si ẹniti o gbà ọlá yi fun ara rẹ̀, bikoṣe ẹniti a pè lati ọdọ Ọlọrun wá, gẹgẹ bi a ti pè Aaroni. Bẹ̃ni Kristi pẹlu kò si ṣe ara rẹ̀ logo lati jẹ́ Olori Alufa; bikoṣe ẹniti o wi fun u pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. Bi o ti wi pẹlu nibomiran pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀, Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya; Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀: Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.
Kà Heb 5
Feti si Heb 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 5:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò