Nipa igbagbọ́ ni Mose, nigbati o dàgba, o kọ̀ ki a mã pè on li ọmọ ọmọbinrin Farao; O kuku yàn ati mã bá awọn enia Ọlọrun jìya, jù ati jẹ fãji ẹ̀ṣẹ fun igba diẹ; O kà ẹ̀gan Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitoriti o nwo ère na. Nipa igbagbọ́ li o kọ̀ Egipti silẹ li aibẹ̀ru ibinu ọba: nitoriti o duro ṣinṣin bi ẹniti o nri ẹni airi. Nipa igbagbọ́ li o dá ase irekọja silẹ, ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ, ki ẹniti npa awọn akọbi ọmọ ki o má bã fi ọwọ́ kàn wọn.
Kà Heb 11
Feti si Heb 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 11:24-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò