NJẸ igbagbọ́ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri. Nitori ninu rẹ̀ li awọn alàgba ti ni ẹri rere. Nipa igbagbọ́ li a mọ̀ pe a ti da aiye nipa ọ̀rọ Ọlọrun; nitorina ki iṣe ohun ti o hàn li a fi dá ohun ti a nri. Nipa igbagbọ́ ni Abeli ru ẹbọ si Ọlọrun ti o san ju ti Kaini lọ, nipa eyiti a jẹri rẹ̀ pe olododo ni, Ọlọrun si njẹri ẹ̀bun rẹ̀: ati nipa rẹ̀ na, bi o ti kú ni, o nfọhùn sibẹ̀. Nipa igbagbọ́ li a ṣí Enoku nipò pada ki o máṣe ri ikú; a kò si ri i, nitoriti Ọlọrun ṣí i nipò pada: nitori ṣaju iṣipopada rẹ̀, a jẹrí yi si i pe o wù Ọlọrun. Ṣugbọn li aisi igbagbọ́ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ̀ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ́ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.
Kà Heb 11
Feti si Heb 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 11:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò