Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin. Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn. Nwọn ni ẹ̀ru, nwọn si fò ni laiyà: idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yio ma ti inu wọn jade. Ẹṣin wọn pẹlu yara jù ẹkùn lọ, nwọn si muná jù ikõkò aṣãlẹ lọ: ẹlẹṣin wọn yio si tàn ara wọn ka, ẹlẹṣin wọn yio si ti ọ̀na jijìn rére wá; nwọn o si fò bi idì ti nyára lati jẹun. Gbogbo wọn o si wá fun ìwa-ipá; iwò oju wọn o si wà siwaju, nwọn o si kó igbèkun jọ bi yanrìn. Nwọn o si ma fi awọn ọba ṣẹsín, awọn ọmọ alade yio si di ẹni-ẹ̀gan fun wọn: gbogbo ibi agbara ni nwọn o si fi rẹrin; nitoripe nwọn o ko erupẹ̀ jọ, nwọn o si gbà a. Nigbana ni inu rẹ̀ yio yipadà, yio si rekọja, yio si ṣẹ̀, ni kikà agbara rẹ̀ yi si iṣẹ òriṣa rẹ̀.
Kà Hab 1
Feti si Hab 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Hab 1:5-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò