Ọlọrun si wi fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, pe, Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin; Ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin; ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ẹranko aiye pélu nyin; lati gbogbo awọn ti o ti inu ọkọ̀ jade, titi o fi de gbogbo ẹranko aiye. Emi o si ba nyin dá majẹmu mi; a ki yio si fi kíkun-omi ké gbogbo ẹdá kuro mọ́; bẹ̃ni kíkun-omi ki yio sí mọ́, lati pa aiye run. Ọlọrun si wipe, Eyiyi li àmi majẹmu mi ti mo ba nyin dá, ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin, fun atirandiran: Mo fi òṣumare mi si awọsanma, on ni yio si ma ṣe àmi majẹmu mi ti mo ba aiye dá. Yio si ṣe, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òṣumare na li awọsanma: Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹnyin, ati gbogbo ọkàn alãye ni gbogbo ẹdá; omi ki yio si di kíkun mọ́ lati pa gbogbo ẹdá run. Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye. Ọlọrun si wi fun Noa pe, Eyiyi li àmi majẹmu na, ti mo ba ara mi ati ẹdá gbogbo ti o wà lori ilẹ dá.
Kà Gẹn 9
Feti si Gẹn 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 9:8-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò