Gẹn 50

50
1JOSEFU si ṣubu lé baba rẹ̀ li oju, o si sọkun si i lara, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
2Josefu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki nwọn ki o kùn baba on li ọṣẹ: awọn oniṣegun si kùn Israeli li ọṣẹ.
3Nwọn si kún ogoji ọjọ́ fun u; nitoripe bẹ̃li a ikún ọjọ́ awọn ti a kùn li ọṣẹ: awọn ara Egipti si ṣọ̀fọ rẹ̀ li ãdọrin ọjọ́.
4Nigbati ọjọ́ ọ̀fọ rẹ̀ kọja, Josefu sọ fun awọn ara ile Farao pe, Njẹ bi emi ba ri ore-ọfẹ li oju nyin emi bẹ̀ nyin, ẹ wi li eti Farao pe,
5Baba mi mu mi bura wipe, Kiyesi i, emi kú: ni isà mi ti mo ti wà fun ara mi ni ilẹ Kenaani, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o sin mi. Njẹ nitorina emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o goke lọ, ki emi ki o si lọ isin baba mi, emi o si tun pada wá.
6Farao si wipe, Goke lọ, ki o si sin okú baba rẹ, gẹgẹ bi o ti mu ọ bura.
7Josefu si goke lọ lati sin baba rẹ̀: ati gbogbo awọn iranṣẹ Farao, ati awọn àlagba ile rẹ̀, ati gbogbo awọn àlagba ilẹ Egipti si bá a goke lọ.
8Ati gbogbo awọn ara ile Josefu, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ara ile baba rẹ̀: kìki awọn ọmọ wẹ́wẹ wọn, ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ni nwọn fi silẹ ni ilẹ Goṣeni.
9Ati kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin si bá a goke lọ: ẹgbẹ nlanla si ni ẹgbẹ na.
10Nwọn si dé ibi ilẹ ipakà Atadi, ti o wà li oke Jordani, nibẹ̀ ni nwọn si gbé fi ohùn rére ẹkún nlanla ṣọ̀fọ rẹ̀: o si ṣọ̀fọ fun baba rẹ̀ li ọjọ́ meje.
11Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani.
12Awọn ọmọ rẹ̀ si ṣe bi o ti fi aṣẹ fun wọn:
13Nitori ti awọn ọmọ rẹ̀ mú u lọ si ilẹ Kenaani, nwọn si sin i ninu ihò oko Makpela, ti Abrahamu rà pẹlu oko fun iní ilẹ isinku, lọwọ Efroni ara Hitti, niwaju Mamre.
14Josefu si pada wá si Egipti, on ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o bá a goke lọ lati sin baba rẹ̀, lẹhin ti o ti sin baba rẹ̀ tán.
Josẹfu tún Dá Àwọn Arakunrin Rẹ̀ Lọ́kànle
15Nigbati awọn arakunrin Josefu ri pe baba wọn kú tán, nwọn wipe, Bọya Josefu yio korira wa, yio si gbẹsan gbogbo ibi ti a ti ṣe si i lara wa.
16Nwọn si rán onṣẹ tọ̀ Josefu lọ wipe, Baba rẹ ti paṣẹ ki o tó kú pe,
17Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u.
18Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ pẹlu, nwọn wolẹ niwaju rẹ̀: nwọn si wipe, Wò o, iranṣẹ rẹ li awa iṣe.
19Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun?
20Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là.
21Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.
Ikú Josẹfu
22Josefu si joko ni Egipti, on ati ile baba rẹ̀: Josefu si wà li ãdọfa ọdún.
23Josefu si ri awọn ọmọloju Efraimu ti iran kẹta; awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse li a si gbé kà ori ẽkun Josefu pẹlu.
24Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.
25Josefu si mu awọn ọmọ Israeli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ.
26Bẹ̃ni Josefu kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún: nwọn si kùn u li ọṣẹ, a si tẹ́ ẹ sinu posi ni Egipti.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 50: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀