Gẹn 5:1-27

Gẹn 5:1-27 YBCV

EYI ni iwe iran Adamu: Li ọjọ́ ti Ọlọrun dá ọkunrin, li aworan Ọlọrun li o dá a. Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn. Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ ti Adamu wà si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé ọgbọ̀n: o si kú. Seti si wà li ọgọrun ọdún o lé marun, o si bí Enoṣi: Seti si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé meje lẹhin ti o bí Enoṣi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Ati gbogbo ọjọ́ Seti jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdun o lé mejila: o si kú. Enoṣi si wà li ãdọrun ọdún, o si bí Kenani: Enoṣi si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé mẹ̃dogun lẹhin ti o bí Kenani, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Enoṣi si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé marun: o si kú. Kenani si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Mahalaleli: Kenani si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ogoji lẹhin ti o bí Mahalaleli, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Kenani si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé mẹwa: o si kú. Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi: Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Mahalaleli si jẹ ẹ̃dẹgbẹ̀run ọdún o dí marun: o si kú. Jaredi si wà li ọgọjọ ọdún o lé meji, o si bí Enoku: Jaredi si wà li ẹgbẹrin ọdún lẹhin igbati o bì Enoku, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Jaredi si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mejidilogoji: o si kú. Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela: Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji: Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki: Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa