O si ṣe, bi nwọn ti ndà àpo wọn, wò o, ìdi owo olukuluku wà ninu àpo rẹ̀: nigbati awọn ati baba wọn si ri ìdi owo wọnni, ẹ̀ru bà wọn. Jakobu baba wọn si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin gbà li ọmọ: Josefu kò sí; Simeoni kò si sí; ẹ si nfẹ́ mú Benjamini lọ: lara mi ni gbogbo nkan wọnyi pọ̀ si. Reubeni si wi fun baba rẹ̀ pe, Pa ọmọ mi mejeji bi emi kò ba mú u fun ọ wá: fi i lé mi lọwọ, emi o si mú u pada fun ọ wá. On si wipe, Ọmọ mi ki yio bá nyin sọkalẹ lọ; nitori arakunrin rẹ̀ ti kú, on nikan li o si kù: bi ibi ba bá a li ọ̀na ti ẹnyin nlọ, nigbana li ẹnyin o fi ibinujẹ mú ewú mi lọ si isà-okú.
Kà Gẹn 42
Feti si Gẹn 42
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 42:35-38
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò