Gẹn 37:2-11

Gẹn 37:2-11 YBCV

Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn. Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u. Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia. Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i. O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá. Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi. Awọn arakunrin rẹ̀ si wi fun u pe, Iwọ o ha jọba lori wa bi? tabi iwọ o ṣe olori wa nitõtọ? nwọn si tun korira rẹ̀ si i nitori alá rẹ̀ ati nitori ọ̀rọ rẹ̀. O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi. O si rọ́ ọ fun baba rẹ̀, ati fun awọn arakunrin rẹ̀: baba rẹ̀ si bá a wi, o si wi fun u pe, Alá kili eyi ti iwọ lá yi? emi ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ yio ha wá nitõtọ, lati foribalẹ fun ọ bi? Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.