Gẹn 37:19-28

Gẹn 37:19-28 YBCV

Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá. Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri. Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀. Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ. O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀; Nwọn si mú u, nwọn si gbe e sọ sinu ihò kan: ihò na si gbẹ, kò li omi. Nwọn si joko lati jẹun: nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn si wò, si kiyesi i, ọwọ́-èro ara Iṣmaeli nti Gileadi bọ̀; ti awọn ti ibakasiẹ ti o rù turari ati ikunra ati ojia, nwọn nmú wọn lọ si Egipti. Judah si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ere ki li o jẹ́ bi awa ba pa arakunrin wa, ti a si bò ẹ̀jẹ rẹ̀? Ẹ wá ẹ jẹ ki a tà a fun awọn ara Iṣmaeli ki a má si fọwọ wa kàn a; nitori arakunrin wa ati ara wa ni iṣe. Awọn arakunrin rẹ̀ si gbà tirẹ̀. Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti.