Gẹn 36
36
Àwọn Ìran Esau
(I. Kro 1:34-37)
1WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu.
2Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi;
3Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu.
4Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli;
5Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani.
6Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀.
7Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn.
8Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu.
9Wọnyi si ni iran Esau, baba awọn ara Edomu, li oke Seiri:
10Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau.
11Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi.
12Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau.
13Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau.
14Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora.
15Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori,
16Kora olori, Gatamu olori, Amaleki olori: wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Elifasi wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Ada.
17Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli ọmọ Esau; Nahati olori, Sera olori, Ṣamma olori, Misa olori; wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Reueli wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau.
18Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana.
19Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn.
Àwọn Ìran Seiri
(I. Kro 1:38-42)
20Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana,
21Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu.
22Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna.
23Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu.
24Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀.
25Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana.
26Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani.
27Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani.
28Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani.
29Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori,
30Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.
Àwọn Ọba Edomu
(I. Kro 1:43-54)
31Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli.
32Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba.
33Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.
34Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀.
35Huṣamu si kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ẹniti o kọlù Midiani ni igbẹ́ Moabu si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Afiti.
36Hadadi si kú, Samla ti Masreka si jọba ni ipò rẹ̀.
37Samla si kú, Ṣaulu ti Rehobotu leti odò nì si jọba ni ipò rẹ̀.
38Ṣaulu si kú, Baal-hanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀.
39Baal-hanani ọmọ Akbori si kú, Hadari si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pau; Mehetabeli si li orukọ aya rẹ̀, ọmọbinrin Metredi, ọmọbinrin Mesahabu.
40Wọnyi si li orukọ awọn olori ti o ti ọdọ Esau wá, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ipò wọn, nipa orukọ wọn; Timna olori, Alfa olori, Jeteti olori;
41Aholibama olori, Ela olori, Pinoni olori;
42Kenasi olori, Temani olori, Mibsari olori;
43Magdieli olori, Iramu olori: wọnyi li awọn olori Edomu, nipa itẹ̀dó wọn ni ilẹ iní wọn: eyi ni Esau, baba awọn ara Edomu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Gẹn 36: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.