Nigbati obinrin na si ri pe, igi na dara ni jijẹ, ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a ifẹ lati mu ni gbọ́n, o mu ninu eso rẹ̀ o si jẹ, o si fi fun ọkọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, on si jẹ. Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn. Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà. OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà? O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́. O si wi pe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wà ni ìhoho? iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ kò gbọdọ jẹ? Ọkunrin na si wipe, Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ. OLUWA Ọlọrun si bi obinrin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obinrin na si wipe, Ejò li o tàn mi, mo si jẹ.
Kà Gẹn 3
Feti si Gẹn 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 3:6-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò