EJÒ sa ṣe alarekereke jù ẹranko igbẹ iyoku lọ ti OLUWA Ọlọrun ti dá. O si wi fun obinrin na pe, õtọ li Ọlọrun wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ gbogbo eso igi ọgbà? Obinrin na si wi fun ejò na pe, Awa a ma jẹ ninu eso igi ọgbà: Ṣugbọn ninu eso igi nì ti o wà lãrin ọgbà Ọlọrun ti wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn a, ki ẹnyin ki o má ba kú. Ejò na si wi fun obinrin na pe, Ẹnyin ki yio ku ikú kikú kan. Nitori Ọlọrun mọ̀ pe, li ọjọ́ ti ẹnyin ba jẹ ninu rẹ̀, nigbana li oju nyin yio là, ẹnyin o si dabi Ọlọrun, ẹ o mọ̀ rere ati buburu.
Kà Gẹn 3
Feti si Gẹn 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 3:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò