O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́.
Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo:
O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀:
O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ.
O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi?
Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi.
Isaaki si wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Ẽti ri ti iwọ fi tete ri i bẹ̃, ọmọ mi? on si wipe, Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u tọ̀ mi wá ni.
Isaaki si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, sunmọ mi, ki emi ki o fọwọbà ọ, ọmọ mi, bi iwọ iṣe Esau, ọmọ mi nitotọ, bi bẹ̃kọ.
Jakobu si sunmọ Isaaki baba rẹ̀, o si fọwọbà a, o si wipe, Ohùn Jakobu li ohùn, ṣugbọn ọwọ́ li ọwọ́ Esau.
On kò si mọ̀ ọ, nitoriti ọwọ́ rẹ̀ ṣe onirun, bi ọwọ́ Esau, arakunrin rẹ̀: bẹ̃li o sure fun u.
O si wipe, Iwọ ni Esau ọmọ mi nitotọ? o si wipe, emi ni.