ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo.
Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi;
Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé:
Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi.
Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá?
Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀.
OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá.
Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀.
Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi.
Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori.
O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi.
O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi.
Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi:
Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi.
O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀.
Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke.
Iranṣẹ na si sure lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nmu omi diẹ ninu ladugbo rẹ.
O si dahùn pe, Mu, oluwa mi: o si yara, o sọ̀ ladugbo rẹ̀ ka ọwọ́, o si fun u mu.
Nigbati o si fun u mu tan, o si wipe, Emi o pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu, titi nwọn o fi mu tan.
O si yara, o si tú ladugbo rẹ̀ sinu ibumu, o si tun pada sure lọ si kanga lati pọn omi, o si pọn fun gbogbo awọn ibakasiẹ rẹ̀.
Ọkunrin na si tẹjumọ ọ, o dakẹ, lati mọ̀ bi OLUWA mu ìrin on dara, bi bẹ̃kọ.
O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa;
O si bi i pe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi: àye wà ni ile baba rẹ fun wa lati wọ̀ si?
On si wi fun u pe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Milka, ti o bí fun Nahori, li emi iṣe.
O si wi fun u pe, Awa ni koriko ati sakasáka tó pẹlu, ati àye lati wọ̀ si.
Ọkunrin na si tẹriba, o si sìn OLUWA.
O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi.
Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀.
Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga.
O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na.
O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ.
Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀.
A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi.
O si wipe, Ọmọ-ọdọ Abrahamu li emi iṣe.
OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.
Sara, aya oluwa mi, si bí ọmọ kan fun oluwa mi nigbati on (Sara) gbó tán: on li o si fi ohun gbogbo ti o ni fun.
Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé:
Bikoṣe ki iwọ ki o lọ si ile baba mi, ati si ọdọ awọn ibatan mi, ki o si fẹ́ aya fun ọmọ mi.
Emi si wi fun oluwa mi pe, Bọya obinrin na ki yio tẹle mi.
O si wi fun mi pe, OLUWA, niwaju ẹniti emi nrìn, yio rán angeli rẹ̀ pelu rẹ, yio si mu ọ̀na rẹ dara; iwọ o si fẹ́ aya fun ọmọ mi lati ọdọ awọn ibatan mi, ati lati inu ile baba mi:
Nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ninu ibura mi yi, nigbati iwọ ba de ọdọ awọn ibatan mi; bi nwọn kò ba si fi ẹnikan fun ọ, ọrùn rẹ yio si mọ́ kuro ninu ibura mi.
Emi si de si ibi kanga loni, mo si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, bi iwọ ba mu ọ̀na àjo mi ti mo nlọ nisisiyi dara:
Kiyesi i, mo duro li ẹba kanga omi; ki o si ṣẹ, pe nigbati wundia na ba jade wá ipọn omi, ti mo ba si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi li omi diẹ ki emi mu lati inu ladugbo rẹ;
Ti o si wi fun mi pe, Iwọ mu, emi o si pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu: ki on na ki o ṣe obinrin ti OLUWA ti yàn fun ọmọ oluwa mi.
Ki emi ki o si tó wi tán li ọkàn mi, kiyesi i, Rebeka jade de ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀; o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o pọn omi: emi si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi mu omi.
O si yara, o si sọ ladugbo rẹ̀ kalẹ kuro li ejika rẹ̀, o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu; bẹ̃li emi mu, o si fi fun awọn ibakasiẹ mu pẹlu.
Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀.
Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá.
Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi.
Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ.
Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi.